WỌN JI IYAALE ILE GBE NIBI TO TI N ṢE ERE IDARAYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, July 30, 2019

WỌN JI IYAALE ILE GBE NIBI TO TI N ṢE ERE IDARAYA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ ni wọn ko tii ri iyaale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Gbemisọla Alabi, ẹni ti wọn loo jade nile laarọ ọjọ Aiku tii ṣe ijẹta lati ṣe ere idaraya (exercise) diẹ, to si jẹ pe latigba to ti jade ni ko ti i rii titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan.

Gbajugbaja oniroyin kan niluu Ekoo, Soni Irabọr lo gbe iroyin naa sita lori ikanni ayelujara ti Facebook rẹ lati fi to gbogbo agbaye leti, bo ya o ṣe e ṣe ki wọn ba wọn ri i, tabi mọ ibi to wa.

Ohun ta a gbọ ni pe opopona Monastery nitosi Novare mall – shoprite to wa lagbegbe Ṣangotẹdo niluu Ajah ni Gbemisọla ti lọọṣe ere idaraya naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI