GBAJUMỌ TOYIN IGBIRA TI KU O, AṢIRI IKU TO PA RE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 22, 2019

GBAJUMỌ TOYIN IGBIRA TI KU O, AṢIRI IKU TO PA RE E

Odu ni Alaaja Mọnsurat Aṣhabi Oluwatoyin Oyemade Rufai Abraham tọpọ awọn eeyan tun mọ si Toyin Igbira ninu awọn jadejade, paapaa niluu Eko, tawọn eeyan si mọn ọn daadaa.

Eyi lo fa a to fi jẹ pe pupọ ninu awọn to mọ obinrin naa lo n ṣe kayeefi pẹluu bi iroyin iku ẹ ṣe tan jade sita, to si mu kawọn kan maa sọ pe ko le ri bẹẹ.

Ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja yi la gbọ pe Toyin Igbira jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56). Aisan agọ ara kan ti wọn lo ti n ba a finra lati bi ọdun marun sẹyin la gbọ pe o pada ṣeku pa a.

Fawọn to ba mọ Oloogbe yi daadaa, wọn a mọ pe ọpọ igba lawọn ọlọpaa atawọn ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro ti mu un fun gbigbe oogun oloro.

Lọdun bii marun sẹyin la gbọ pe aisan nla kan kọluu, to si gba ilu oyinbo lati lọọ tọju ara rẹ, ṣugbọn lọdun meji sẹyin niroyin tun jade nipa rẹ pe ara rẹ ti n ya, to si jẹ pe aisan naa n ba finra gidi gan an, ko too pada ran an lọ sọrun lọsẹ to kọja yi.

Nibi ti Toyin Igbira lọwọ de, awọn olorin kii fi ṣere rara, bẹẹ la gbọ pe bo ṣe ni ile olowo nla siluu Eko, bẹẹ lo ni siluu Abuja, to si tun ra ile siluu London pẹluu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI