NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN WỌ DAVIDO LỌ SILE ẸJỌ NI TIPATIPA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, July 22, 2019

NITORI ẸSUN JIBITI, WỌN WỌ DAVIDO LỌ SILE ẸJỌ NI TIPATIPA

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afaimọ ni ki gbajugbaja olorin takasufe nni, David Adedeji Adeleke tọpọ awọn ololufẹ ẹ tun mọ si Davido ma pada ṣẹwọn, iyẹn bi ko ba yọju sile ẹjọ majisireeti to wa ni Igboṣere niluu Eko lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ọdun yi, latari ẹsun jibiti owo to lu, eyi ti wọn fi kan an.

 
Iyalẹnu lọrọ owo ti wọn ni Davido lu ọdọmọkunrin olorin kan toun na ṣẹṣẹ n dide bọ kan, ti wọn si ni miliọnu mẹrin naira pere lowo naa. To si jẹ pe gbogbo awọn ti wọn n pe e lori ọrọ naa lati oṣu kinni in ọdun yi ni ko da wọn lohun.

 
Ọjọ kẹtalelogun oṣu karun un ọdun yi la gbọ pe wọn wọ Davido, amugbalẹgbẹ ẹ, Busari Idris Temitọpẹ ti wọn tun n pe ni Aloma ati ileeṣẹ ẹ, Davido Music Worldwide Limited lọ si kọọtu latari ẹsun jibiti naa pẹluu iwe ẹsun MCL/702/19.

 
Wọn ni Davido atawọn tọrọ naa kan ko yọju, bẹẹ ni ko tun ran agbẹjọro ẹ lati yọju si kọọt, to si mu ki Onidajọ naa sọ pe ki wọn lọ tun un pe wa lati yọju, ṣugbọn ti ko ṣe bẹẹ.

Ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Andre-Tejiri Ochuko Ibhihwiori to filuu Oyinbo ṣebugbe ni wọn loo pe Davido pe ko wa a kopa ninu orin oun tuntun toun fẹẹ gbe jade, ti wọn si ni Davido loun yoo gba owo koun too le kopa, eyi lo mu ki Andre-Tejiri san owo naa.

 
Iyalẹnu lo jẹ pe Davido ko yọju sibi ti wọn ti ṣe orin naa, to si tun kọ lati da owo naa pada fun un.

Ni bayii, ile ẹjọ ti sọ pe dandan ni ki Davido yọju lati nnkan to ri lọbẹ to fi wa iru sọwọ lọjọ kẹtalelogun oṣu to n bọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI