GBOGBO ÀWỌN OBÌNRIN NI WỌ́N N YÓÒ JẸ ÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌJỌBA DAPỌ̀ ABÍỌ́DÚN - IGBÁKEJÌ GÓMÌNÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 6, 2019

GBOGBO ÀWỌN OBÌNRIN NI WỌ́N N YÓÒ JẸ ÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌJỌBA DAPỌ̀ ABÍỌ́DÚN - IGBÁKEJÌ GÓMÌNÀ

Igbakeji Gomina Ipinlẹ Ogun, Onímọ̀-ẹ̀rọ Nọimọt Salakọ-Oyedele tí fi ọkàn gbogbo àwọn obìnrin patapata nipinlẹ Ogun balẹ pe gbogbo wọn ni yoo jẹ anfaani mudunmudun iṣejọba Dapọ Abiọdun, nitori pe gbogbo awọn obinrin to ba kun oju oṣuwọn ni wọn yoo yan lati ṣoju wọn.

O fọkan wọn balẹ lasiko to n gba awọn aṣoju obinrin ninu ẹsin Islam, iyẹn Federation of Muslim Women’s Association in Nigeria (FOMWAN), ẹka tipinlẹ Ogun lalejo ni ọfiisi ẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

Igbimọ naa ti Alaaja Kudirat Yẹni Rabiu lewaju wọn la gbọ pe wọn ṣe abẹwo 'ẹ ku oriire' lọọ ki igbakeji Gomina, paapaa lati fi idunnu wọn han, nibẹ ni wọn si ti sọ pe awọn wa lẹyin ijọba yi digbi.

Igbakeji Gomina sọ pe gbogbo awọn nnkan ti kii jẹ kawọn obinrin ni aṣoju gidi ninu iṣejọba ni wọn ti fi to wọn leti, tawọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati yan awọn to ṣe e fọkan tan sipo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI