MIKẸL TI FARAPA O, WỌN NI KO NII KOPA NIBI IFIGAGBAGA PẸLUU CAMEROON - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, July 6, 2019

MIKẸL TI FARAPA O, WỌN NI KO NII KOPA NIBI IFIGAGBAGA PẸLUU CAMEROON

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ki gbogbo awọn to ti n gbaradi lati wo idijẹ ti yoo waye laarin ikọ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ati ikọ agbabọọlu Indomitable Lions ti orilẹede Cameroon laago mẹrin oni mọ pe balogun Super Eagles, Mikel Obi ko nii kopa ninu idije naa.

A gbọ pe Mikel farapa nibi idje to wa laarin Super Eagles ati Madagascar to pari si aami ayo meji si odo, nibẹ lo ti fi orunkun ẹ ṣeṣe.

Bo ṣe farapa naa lo mu ki akọimọn-gba wọn, Gernot Rohr yọ nigba ti idije naa wọ iṣeju mọkandinlọgọta. A tun gbọ pe o ṣe e ṣe ki Mikẹl ma kopa titi idije AFCON2019 yoo fi pari, iyẹn bi wọn ba bori nirọlẹ onii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI