EEDRIS ABDULKAREEM PADANU MAMA Ẹ, LOJU ẸSẸ NI WỌN TI SIN-IN - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, July 14, 2019

EEDRIS ABDULKAREEM PADANU MAMA Ẹ, LOJU ẸSẸ NI WỌN TI SIN-IN

Ibanujẹ ọkan naa ko tii tan lara gbajugba ati ilu mọn ọn ka olorin nni, Eedris Abdulkareem titi di asiko ti a kọ iroyin yi tan, latari bo ṣe padanu mama ẹ, Alaaja Safurat Ajọkẹ Ajenifuja lọjọ Ẹti ijẹta.

Alaaja Safurat la gbọ pe o ku lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun un siluu Eko, lẹyin aisan ọjọ ogbo.

Ninu ọrọ ti gbajugba olorin naa, Eedris kọ sori ikanni ayelujara ẹ lo jẹ ko di mimọ pe ko tii sẹni naa toun le fi rọpo mama oun, latari awọn iya to jẹ lori oun lati di olori-ire lawujọ.

Eedris Abdulkareem loses mother 
Mama naa la gbọ pe o pẹluu ọkan lara awọn ti wọn tẹle Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti lati ja fun ẹtọ awọn araalu lasiko Ọba Adwọle keji, lọdun 1949.

Aago mọkanla ku iṣẹju marundinlogun (10.35pm) ni mama naa ki aye pe o digboṣe nigba ti ọlọjọ de. Itẹkuu Atan, to wa ni Akọka nipinlẹ Ekoo ni wọn ti tẹ mama naa si afẹfẹ ire lọjọ Abamẹta ana an.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI