KAYEEFI NLA RE O: IBRAHIM JI ABURO RẸ GBE, LO BA TUN PA A DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, July 12, 2019

KAYEEFI NLA RE O: IBRAHIM JI ABURO RẸ GBE, LO BA TUN PA A DANU

Ṣe wọn sọ pe adiẹ kii jẹ ifun ara wọn ni, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ nigba ti ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Kano tẹ ọdọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Ibrahim Ahmad ti wọn loo ji aburo rẹ, ọmọdun marun gbe, to si tun pa a danu nigba ti ko tete ri owo to n beere gba lowo awọn obi wọn.

 
Ana tii ṣe Ọjọbọ ni Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Kano, Ahmed Iliyasu lewaju awọn ọlọpaa ẹ, atawọn ọdaran naa lọọ hu oku ọmọdekunrin naa nibi ti wọn sin in si.

 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni lọsẹ to kọja ni Ibrahim lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji kan, Abdulmajid Mohd ati Musa Sanusi ti wọn jẹ ọmọdun mejidinlogun lati ji aburo rẹ, Ahmed Ado gbe, kawọn le fi ri owo.


 
Ileewe ti ọmọ naa n lọ, iyẹn ileewe alakọbẹrẹ Ma'ahat to wa ni Karkasara ni wọn sọ pe Ibrahim ti lọọ mu Ahmed pẹluu ẹtanjẹ pe oun fẹẹ mu lọ sile, to si jẹ pe inu ile akọku kan to wa ni Sheka ni wọn gbe ọmọ naa lọ lati lọ maa pe awọn obi wọn pe awọn ti ji Ahmed gbe, awọn yo o si gba aadọta miliọnu (50m) naira kawọn to le fi silẹ.


 
Wọn ni nigba ti wọn duna-dura titi ni wọn gba lati gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun (100,00) naira, ati pe bawọn ko ba tete ri owo naa gba, awọn yoo pa Ahmed danu, ta a si gbọ pe wọn fun ọmọ naa ni 'igbo' mu.


 
Igbo naa ni wọn loo yi ọmọdun marun un yi lori, to si gbabẹ jade laye, eyi ni wọn loo mu ki wọn dẹkun lati maa beere owo naa, ti wọn si lawọn ko nilo owo naa mọ, tori pe wọn ko tete dawọn lohun.


 
Loju ẹsẹ ti wọn lọmọ naa ti dakẹ, la gbọ pe wọn ti gbe e lọ sile akọku kan to wa lagbegbe Sheka, nibẹ ni wọn si lọọ ri oku ẹ sii.


 
Bi ọrọ naa ṣe n lọ lọwọ, la gbọ pe awọn obi wọn ti lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ta a si gbọ pe awọn ọlọpaa ni wọn ṣewadi foonu naa de ibi ti wọn wa, tọwọ si tẹ wọn.

Bi ọwọ ṣe tẹ wọn ni wọn bẹrẹ sii bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe eremọde lasan lawọn n ṣe, awọn ko nilo owo naa rara.

Ni bayii, Ahmed Iliyasu to jẹ Komiṣana ọlọpaa ipinlẹ Kano ti sọ pe bawọn ọdaran naa ba de ile ẹjọ, ki wọn lọ maa bẹ adajọ, tori pe adajọ nikan lo le yọ wọn ninu iwa ọdaran wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI