KO WA TAN BI: IJỌBA APAPỌ LE AWỌN TO N JẸ ANFAANI N-POWER LỌNA AITỌ DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 25, 2019

KO WA TAN BI: IJỌBA APAPỌ LE AWỌN TO N JẸ ANFAANI N-POWER LỌNA AITỌ DANU

Ko din ni ẹgbẹrun meji ati igba (2,525) awọn ti wọn sọ pe wọn n jẹ anfaani irolagbara ti ijọba ṣe agbekalẹ ẹ lọdun meloo kan sẹyin, iyẹn N-POWER lọna aitọ danu, ti wọn si ti wọgi le bi wọn ṣe gba wọn siṣẹ.

A gbọ pe awọn ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) lawọn ti wọn gba wọle nigba ti eto naa bẹrẹ kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ 774 to wa lorilẹede yi, ti wọn si n gba owo oṣu wọn, ṣugbọn iyalẹnu ni wọn loo jẹ nigba ti wọn sọ pe awọn kan ko lọ sibi ti wọn pin wọn si lati maa ṣiṣẹ, ti wọn si n gba owo oṣu.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) naira lowo ọya ti ẹni kọọkan n gba gẹgẹ bi alakalẹ ijọba latigba ti wọn ti bẹrẹ lọdun 2016 lti fi ran awọn ọdọ ti wọn ko niṣẹ lọwọ.

Ijọba apapọ si ti sọ pe awọn ti ṣetan lati maa gbogun ti awọn iwa ẹtanjẹ ati aiṣe ojuṣe awọn eeyan bayii, lati le din iwa ajẹbanu ku lawujọ wa.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ,  Onidajọ Bibiye to jẹ agbẹnusọ fun National Social Investment Office sọ pe awọn ti ko din ni 18,674 ni wọn ti finufẹdọ kọwe fiṣẹ naa silẹ, nigba ti wọn ti ri iṣẹ gidi, tawọn min si n gba owo ti ko tọ si wọn lẹyin ti wọn ko lọ sibi ti wọn pin wọn si mọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI