MO KABAMỌ PE MI O KỌJU MỌ ẸKỌ MI NILEEWE GIRAMA - GBAJUMỌ OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Tuesday, July 16, 2019

MO KABAMỌ PE MI O KỌJU MỌ ẸKỌ MI NILEEWE GIRAMA - GBAJUMỌ OṢERE TIATA

Ọkan pataki lara awọn oṣere tiata orilẹede Ghana nni, to tun jẹ gbajumọ nidi iṣẹ naa kaakiri agbaye, Yvonne Nelson ti sọ pe abamọ nla lo n jẹ foun nigba toun ba n ranti pe oun ko kọju mọ ẹkọ oun lasiko toun ṣi wa nile ẹkọ.

Ori ayelujara ni ilu mọn ọn ka oṣerebinrin naa ti sọrọ yi nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹluu oniroyin ileeṣẹ redio Joy FM, nibẹ lo ti sọ pe nnkan kan ṣoṣo to maa n ba oun ninu jẹ lọpọ igba ni pe oun ko gbajumọ ẹkọ oun nileewe girama.

Iya ọlọmọ kan naa sọ pe abamọ yi lo maa n jẹ koun maa ke tantan fawọn ewe ati ọjẹ-wẹwẹ asiko yi pe ki wọn gbajumọ ẹkọ wọn daradara nitori pe nnkan to ṣe pataki ju nigbesi aye ẹda niyẹn.

Nelson tun jẹ ko di mimọ pe nigba ti aaye naa bẹrẹ sii ṣi silẹ pe oun nilo awọn nnkankan to si jẹ mọ ẹkọ, oun ni lati tun sare pada lọọ tun awọn idanwo toun ko ni ṣe, eyi to fẹ ẹ pa iṣẹ toun yan laayo lara.

O sọ ninu ọrọ rẹ pe "Mo maa n lọ ṣe ere itage ni gbogbo ọjọ Abamẹta nigba ti mo ṣi wa nile ẹkọ girama. Mo ni lati tun awọn idanwo kọọkan ṣe. Agbo amuludun ti mo darapọ mọ ni ko fun mi laaye lati gbaju mọ ẹkọ mi daadaa. O rọrun lati kuna lai de ile ẹkọ fasiti.

"Mo kabamọ pe mi o farabalẹ gbaju mọ ọrọ ẹkọ awọn iwe mi, idi ni yii to fi jẹ pe bi mo ba n ṣalabapade awọn ọmọde, mo maa n sọ fun wọn pe ki wọn kọju mọ iwe wọn daadaa.

"Fasiti Central ni mo wa. Ko si rọrun fun mi lati maa ki irin meji bọ inu ina leẹkan ṣoṣo, ṣugbọn ko si nnkan ti mo fẹẹ ṣe, nitori pe mo ti pinu lọkan ara mi. Awọn to n gbe fiimu jade lorilẹede Naijiria maa n fun mi lanfaani to dara julọ, ṣugbọn mo ni lati tẹlẹ ifẹ ọkan mi lori ileewe mi. Inu mi si dun bayii pe mo ti kẹkọọ jade."

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI