AYỌ ABARA TINTIN: ALAAGANNA BI IBEJI SINU IGBO - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Tuesday, July 16, 2019

AYỌ ABARA TINTIN: ALAAGANNA BI IBEJI SINU IGBO

Kayeefi nla lọrọ obinrin alaaganna kan ti wọn loo bimọ, ibeji sinu igbo nipinlẹ Katsina lọsẹ to kọja yi ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa titi dasiko ti a ko iroyin yi jọ.

Bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ ti wọn ni aarun ọpọlọ ti n da obinrin ti a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko yi laamu, ti wọn si loo gbajumọ daadaa nijọba ibilẹ Malumfashin, ipinlẹ Katsina, ṣaddede la gbọ pe wọn ri oyun ninu ẹ.

Mentally challenged woman gives 
Awọn kan la gbọ pe wọn n kọja lọ ninu igbo, to si jẹ pe asiko naa ni wọn ni obinrin alaaganna yi n rọbi lọwọ, ti wọn si ran an lọwọ lati gba ẹbi awọn ọmọ naa.

Titi dasiko ti a fi ko iroyin yi jọ ni wọn ko tii mọ ẹni to fun alagaana naa loyun, depodepo ẹni ti wọn yoo pe ni baba awọn ibeji naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI