O MA ṢE O, GBAJUMỌ ONIROYIN KU NIBI TO TI N JO LOJU AGBO - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, July 14, 2019

O MA ṢE O, GBAJUMỌ ONIROYIN KU NIBI TO TI N JO LOJU AGBO

Bi ala lọrọ naa ṣi n ri titi dasiko ti a ṣajojọpọ iroyin yi tan, latari bi ọkan lara awọn akọroyin nipinlẹ Ẹdo ṣe ṣubu nibi to ti n fẹsẹ ra ijo, to si jẹ pe ibẹ lo gba lọ sọrun alakeji.

"Ko le ri bẹẹ', 'ko le jẹ bẹẹ', 'irọ ni o', 'ẹ jẹ ki n wo o" lọrọ ti wọn lo n tẹnu awọn eeyan jade lọjọ Ẹti to kọja yi nibi ayẹyẹ ọgọta ọdun ti wọn da ileewe kan ti wọn pe orukọ rẹ ni St Maria Goretti, nipinlẹ Ẹdo silẹ.

A gbọ pe ọjọ naa ni wọn ṣayẹyẹ ọgọta ti wọn da ileewe naa silẹ, ti wọn si pe gbogbo awọn akẹkọọ jade lati wa a gbadun ara wọn, kawọn ti wọn ti foju kan ara wọn tipẹ tun le pada foju rira, , eyi ti wọn n pe ni Reunion Party.

Nibi ayẹyẹ naa la gbọ pe awọn akẹkọọ jade ti n fẹsẹ ra ijo sorin taka sufe kan to n lọ lọwọ, ti wọn si ni gbajugbaja oniroyin ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọsarugue Eunice naa jẹ akẹkọọ jade nibẹ.

A gbọ pe nibi to ti n jo lọwọ lo ti ṣubu sori aga ijokoo, to si jẹ pe awọn ti ri i nigba naa ko tete fura pe nnkan ti ṣe e, gbogbo ero ọkan wọn ni pe ṣe lo n sinmi ijo to ti n jo lataarọ.

Nigba ti wọn ko tete ri i pe ko dide, ni wọn ba bẹrẹ sii pe e pe ko dide lati jo, tori ti wọn sọ pe awọn eeyan nifẹ ẹ gan, ati pe oun lawọn eeyan tun daju bo lọjọ naa. Gbogbo bi wọn ṣe sọ pe wọn n pe e ni ko dahun, to si n ya awọn eeyan lẹnu pe ki lo le ṣẹlẹ.

Loju ẹsẹ ti wọn ti ranṣẹ si oniṣegun oyinbo kan to pada sọ pe ki wọn tete gbe e lọ si ọsibitu to ba wa nitosi. Eyi lo mu ki wọn gbe e digbadigba lọ lati doola ẹmi ẹ, nigba ti wọn si maa debẹ, ẹlẹmin ti gba a.

Ọkan lara awọn akẹkọọ jade ileewe naa, oun naa wa nibi iṣẹlẹ naa, iyẹn Uwuma Vincentmba lo yanna-naa gbogbo nnkan to ṣẹlẹ fawọn eeyan sori ayelujara ti Facebook ẹ.

Wọnyi lawọn fidio naa.
Uwuma Vincentba Awala
8 hrs
1 comment2.5K views 


Uwuma Vincentba Awala
8 hrs
1 share1.5K views

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI