ỌBASANJỌ NI IṢORO KAN ṢOṢO TI NAIJIRIA NI, ALAGABAGEBE NI - ỌBA AKINOLU SỌKO ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 8, 2019

ỌBASANJỌ NI IṢORO KAN ṢOṢO TI NAIJIRIA NI, ALAGABAGEBE NI - ỌBA AKINOLU SỌKO ỌRỌ

Ọba Rilwan Akiolu tiluu Ekoo fi ju bọmbuọrọ sita pe Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ nikan ni iṣoro to n koju orilẹ-ede yi.

Laipẹ yi ni Ọba Akinolu sọrọ naa nibi ifilọlẹ tuntun ti ọkan lara awọn agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba gbe jade, eyi to pe ni "Battlelines: Adventures in Journalism and Politics", to waye ni ile igbafẹ tiluu Eko, iyẹn Eko Hotels, Victoria Island.

Apa kan ninu iwe naa ni Ọba Akiolu ti mẹnuba a pe o ti pẹ toun ti mọ pe alagabagebe ni Ọbasanjọ nitori pe ṣe lo tan awọn gomina ẹgbẹ oṣelu AD atawọn ẹgbẹ Afẹnifẹre, ati pe ọlọgbọn rẹpẹtẹ ni Bọla Tinubu.

Ninu ọrọ Ọba Akinolu, o sọ pe " Iṣoro ti a n ni lorilẹ-ede yi, ma a tun ṣi maa tẹnumọ ọn ni gbogbo igba pe iṣoro kan ṣoṣo ti a ni lorilẹ-ede Naijiria ni Ọbasanjọ.

Ọpọ awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni wọn ko le tete pa a de pẹluu nnkan ti Ọba Akinolu ṣo yii, ti ko si sẹni to le sọrọ le e lori.

Lara awọn to wa nibi eto naa ni igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yi, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo; Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Ahmed Lawan; igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ibrahim Wase; Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmẹd Tinubu; Gomina ipinlẹ Bayelsa, Seriake Dickson; awọn gomina ilẹ Yoruba; awọn gomina tẹlẹri, awọn minisita tẹlẹri; awọn ọba alaye atawọn min in.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI