AGUNBANIRỌ TUN KU L'OṢOGBO, OOGUN APẸFỌN TO FI SORI LO ṢEKU PA A - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, July 8, 2019

AGUNBANIRỌ TUN KU L'OṢOGBO, OOGUN APẸFỌN TO FI SORI LO ṢEKU PA A

Kani ọdọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ayọmikun Juliana mọ pe oogun apẹfọn toun fẹẹ fi pa eeṣi (lice) ori oun ni yoo ran oun lọ sọrun apapandodo ni, boya ki ba ti beere oriṣiriṣiri ibeere, tabi ṣe iwadii kikun ko to o loo.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ayọmikun ti wọn ni ile ẹkọ fasiti Tai Ṣolarin to wa niluu Ijẹbu Ijẹbu-Ode lo ti kẹkọọ jade, to si n sin orilẹ-ede baba rẹ niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun lọwọ la gbọ pe ṣe ni eeṣi bo ori rẹ.

Wọn ni ile aṣerunloge kan lo ti lọọ ṣe irun rẹ lai pẹ yi, nigba to si maa tu, ṣe lo rii pe eeṣi naa ti pọ rẹpẹtẹ lori oun, ko da, ti wọn lawọn to n ba a ṣe irun gan an tun sọ fun un pe ko wa nnkan ṣe sii ko too pẹ ju.

Wọn ni kaka ki Ayọmikun lọọ ra ọṣẹ ti wọn fi n fọ irun, paapaa eeṣi kuro lori, oogun apẹfọn, iyẹn Sniper ni wọn lo lọ ọ ra, to si fi pa gbogbo ori rẹ, ko da a, ti wọn ni ṣe lo tun de fila si ko too fi sun lọ.

Aarọ ọjọ keji la gbọ pe nigba tawọn ọrẹ rẹ yoo fi mọ, omi ti n tẹyin wọgbin lẹnu, idi ni yii ti wọn fi sare gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn oju ọna la gbọ pe o ti dakẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI