ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN: ADIGUNJALE TO LỌ FỌ ṢỌỌṢI TUN KỌ LẸTA PE KI WỌN GBADURA F'OUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 17, 2019

ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN: ADIGUNJALE TO LỌ FỌ ṢỌỌṢI TUN KỌ LẸTA PE KI WỌN GBADURA F'OUN

Ṣe lawọn to ri lẹta ti adigunjale kan to lọ fọ ṣọọṣi lalẹ ọjọ Aiku, Sande to kọja yi tun bẹrẹ sii wo tiyanu-tiyanu, nigba to tun bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn gbadura foun nitori pe nnkan toun ro kọ loun ba pade.

 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, adigunjale naa sọ pe ọkan lara awọn ọmọ ṣọọṣi naa lo fun oun lọwọ pe obitibiti owo wa ninu ṣọọṣi naa to wa niluu Engineer, ipinlẹ Nyandarua County, orilẹede Uganda, to si mu koun lọọ yẹẹ wo lalẹ.

Ole naa sọ pe nigba toun jawọ ṣọọṣi naa, toun tu gbogbo inu ẹ finifini, lo jẹ iyalẹnu foun pe ko si nnkan to jọ owo nibẹ, idi ni yii, toun fi fibanujẹ jade sita.

Ninu lẹta naa lo ti sọ pe ẹri ọkan ti ko jẹ koun gbadun lo mu koun kọ lẹta pe ki wọn gbadura foun, ki wọn si dariji oun fun nnkan toun ṣe naa.

Pentecostal Evangelistic Fellowship of Africa (PEFA) lorukọ ṣọọṣi naa.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI