Pupọ awọn to ri ayederu babalawo kan tọwọ ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo kumọkumọ, iyẹn EFCC nibi to ti n sunkun ni wọn tun n gbe e ṣepe nla-nla lọjọ Iṣẹgun ana an, ẹni ti wọn loo ti lu ogunlọgọ awọn eeyan ni jibiti obitibiti owo.
![EFCC Nabs Fake Native Doctor](https://i2.wp.com/www.yabaleftonline.ng/wp-content/uploads/2019/07/66218053_897267100636786_3264538105469150771_n.jpg?resize=640%2C425&ssl=1)
Fatai Ọlalere Aliu ni wọn pe orukọ ayederu babalawo naa, ti wọn ni ẹtanjẹ lo fi n gba owo lọwọ awọn eeyan pe oun fẹẹ tan iṣoro aye wọn. Ile ẹ to wa lagbegbe Kisumu, Odo-Ọna Elewe, Ibadan lawọn EFCC ti lọ ka a mọ.
![EFCC Nabs Fake Native Doctor](https://i0.wp.com/www.yabaleftonline.ng/wp-content/uploads/2019/07/65312034_2384612125196398_8751926720171449386_n.jpg?resize=640%2C425&ssl=1)
A gbọ pe o ti le loṣu meji tawọn ajọ naa fi tọpinpin ẹ ko too di pe wọn lọ ọ ka a mọ, lẹyin ti wọn ri oriṣiriṣi ẹri aridaju ti wọn le fi tako o nile ẹjọ. Iyalẹnu ni wọn lo ojẹ fawọn araadugbo naa nigba ni kete ti wọn tu aṣiri ẹ sita.
![](https://i0.wp.com/www.yabaleftonline.ng/wp-content/uploads/2019/07/65573187_3292008334146436_1760028230435897332_n.jpg?resize=640%2C425&ssl=1)
Oun funra rẹ lo si mu awọn EFCC lọ si ojubọ ẹ to wa ninu igbo kijikiji nla kan to wa loju ọna Ibadan si Ijẹbu-Ode mọ agbegbe Kọbọmọjẹ, nibi to ti n lu awọn eeyan ni jibiti owo pẹluu ẹtanjẹ ati agbari ti wọn lo n lo fun wọn.
![EFCC Nabs Fake Native Doctor](https://i2.wp.com/www.yabaleftonline.ng/wp-content/uploads/2019/07/66716205_450401538850745_6032519092569816873_n.jpg?resize=640%2C425&ssl=1)
Mọto nla bọgini meji ni wọn gba lọwọ ẹ, ti wọn si tun ti awọn ile olowo nla mẹta to kọ kọ siluu Ibadan pa. Iwadii ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
![EFCC Nabs Fake Native Doctor](https://i2.wp.com/www.yabaleftonline.ng/wp-content/uploads/2019/07/66120947_913143279019283_6405159655639404022_n.jpg?resize=640%2C425&ssl=1)
No comments:
Post a Comment