ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ AWỌN ỌDARAN AJINIGBE L'ỌṢUN, BOROBORO NI WỌN N KA BI AJẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 10, 2019

ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ AWỌN ỌDARAN AJINIGBE L'ỌṢUN, BOROBORO NI WỌN N KA BI AJẸ

Boroboro ni Usman Ladan, ọmọ bibi ipinlẹ Ṣokoto n ka lọgba ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun lọjọ Iṣẹgun ana, nigba ti wọn foju ẹ han fawọn oniroyin lẹyin tọwọ tẹ ẹ, to si bẹrẹ sii sọ pe ki wọn foju aanu wo oun.

Ọkan lara awọn ogbologbo ajinigbe nipinlẹ naa ni wọn pe Usman, o si pẹluu awọn to ji Ọjọgbọn Ọlayinka ti Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa n'Ile Ifẹ gbe lọjọ Aiku Sande to kọja yi loju ọna Ibadan siluu Ile-Ifẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iluu Ekoo la gbọ pe Ọjọgbọn Ọlayinka ti n pada lọ siluu Ile-Ifẹ lọjọ Sande naa, kawọn ajinigbe tooo da a duro lọna, lẹyin ti wọn si gba miliọnu marun ataabọ (5.45m) naira lọwọ rẹ ni wọn to ṣẹṣẹ yanda ẹ lati maa lọ.

A gbọ pe ṣe Usman rin gberegbere ko too ko sọwọ ọlọpaa lasiko ti wọn n wa oun atwọn ẹmẹwa ẹ.
 
Nigba to n sọrọ niluu Oṣogbo, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Ige sọ pe yatọ si pe ọwọ tẹ Usman, ọwọ tun tẹ awọn ọdaran min in bii Samaila Gede, ọmọ bibi ipinlẹ Katsina; Kẹmu Rẹjuli, ọmọ bibi orilẹ-ede Niger; Jubril Mohammed toun wa lati ipinlẹ Katsina la gbọ pe awọn agbegbe bii Ikire ati Iwo lọwọ ti tẹ wọn.

Bẹẹ lo sọ pe gbogbo wọn ti jẹwọ pe ọdaran paraku lawọn, to si fi n da gbogbo eeyan loju pe wọn yoo foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI