WỌN TI TU YEWANDE TO GUN ỌKỌ RẸ PA SILẸ L'ẸWỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, July 22, 2019

WỌN TI TU YEWANDE TO GUN ỌKỌ RẸ PA SILẸ L'ẸWỌN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yin, wọn ti tu iyaale ile kan, Yewande Oyediran to gun ọkọ rẹ pa latari aawọ to bẹ silẹ laarin awọn mejeeji niluu Ibadan.

Fawọn ti ko ba tii gbagbe, ọjọ keji, oṣu keji ọdun 2016 ni iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Adeniyi, Abidi-Ọdan, Akobọ niluu Ibadan nigba ti wọn sọ pe Yewande ati ọkọ re to ti doloogbe bayii, Lọwọ Oyediran bẹrẹ sii ba ara wọn fa ọrọ ti ko to n kan.

Loju ẹsẹ la gbọ pe Yewande tọ jẹ ọmọ Ẹni-ọwọ Oyetunde Oyediran ti fa ọbẹ yọ, to si fi gun ọkọ rẹ, titi to fi ku nigba naa lọhun. Ti ile ẹjọ si pada ran an lẹwọn ọdun meje pere lati lọọ fi gbara, iyẹn ninu oṣu kọkanla ọdun 2017.

AWIKONKO gbọ pe ọdun meji pere ni Yewande ti lo lẹwọn ki ijọba Gomina Ajimọbi nipinlẹ Ọyọ too fi oju aanu wo o mọ awọn ẹlẹmin in ko too gbe silẹ loṣu karun ọdun yi.

A gbọ pe pẹluu iranlọwọ baba Yewande atawọn mọlẹbi ẹ ni wọn fi rii gba silẹ.

4 comments:

  1. Mo ki Yewande pe oku orire itusile kuro ni Ogba ewon.

    ReplyDelete
  2. Oriire nla ni o, Olorun ko ni je ko ri iru re mo o.
    Koun naa wa maa se suuru bayii ni o

    ReplyDeletePÍN-IN KÁÀKIRI