SARS YINBỌN PA OṢIṢẸ AGBALẸ IJỌBA L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 15, 2019

SARS YINBỌN PA OṢIṢẸ AGBALẸ IJỌBA L'EKOO

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, lawọn ara adugbo Ajiṣegiri lagbegbe Ilupeju nipinlẹ Eko ṣi n fẹhonu han lori bawọn ọlọpaa kogberegbe, iyẹn SARS ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn to n gba ilẹ opopona kaakiri.

A gbọ pe awọn kan ti n wọn n ta igbo lawọn SARS naa n le kaakiri, ti wọn si da ibọn bolẹ laarin adugbo naa, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹnikẹni mu balẹ ninu wọn.

Lara ibọn ti wọn yin yi, la gbọ pe o ṣeeṣi ba agbalẹ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Francis, to si jẹ pe loju ẹsẹ lo ti ku.

 
Awọn SARS naa la tun gbọ pe wọn ko duro lati doola ẹmi ọdọmọkunrin naa, to si jẹ loju ẹsẹ ni wọn ti na papa bora, ti a si gbọ pe wọn ṣi n wa wọn dasiko yi.

Lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Bala Ẹlkana sọ pe oun ti i gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ati pe oun wa ninu ipade lasiko ti a kọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI