TRIBUNAL: ỌṢHIỌMỌLẸ FOJU BALE ẸJỌ FUN IGBA AKỌKỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 8, 2019

TRIBUNAL: ỌṢHIỌMỌLẸ FOJU BALE ẸJỌ FUN IGBA AKỌKỌ

Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lapapọ, Adams Ọṣhiọmọlẹ fun igba akọkọ lati jẹri gbe Aarẹ Muhammadu Buhari fun ti idibo apapọ to waye loṣu keji ọdun yi.

Oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Alaaji Atiku Abubakar lo gbe ẹgbẹ oṣelu APC ati Aarẹ Buhari lọ sile ẹjọ, nibi to ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC ati ajọ INEC pe magomago ni wọn ṣe lati kede Aarẹ Buhari gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo naa.

Latigba ti wọn ti yan igbimọ ẹlẹni marun un ti yoo ri sọrọ ẹjọ naa nile ẹjọ Tribunal lọjọ kẹwaa oṣu kẹfa to kọja naa lawọn APC ti n mura silẹ lati lọọ sọ tẹnu wọn

Igbimọ naa ni Onidajọ Mohammẹd Garba jẹ alaga wọn. Aago mẹwaa ku iṣẹju mẹrindinlogoji la gbọ pe Ọṣhiọmọlẹ atawọn igbimọ to tẹle e lọ de sinu ọgba kọọtu naa niluu Abuja.

Lara awọn to tun wa nile ẹjọ naa ni: Alaga ajọ EFCC; Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Adamawa, Nuhu Ribadu; Ọkan lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP, Tom Ikimi; Agbẹnusọ f'ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI