WỌNYII NI ẸKUNRẸRẸ ORUKỌ AWỌN ỌỌNI IFẸ MỌKANLELAADỌTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 13, 2019

WỌNYII NI ẸKUNRẸRẸ ORUKỌ AWỌN ỌỌNI IFẸ MỌKANLELAADỌTA

A ti gbiyanju lati mu ẹkunrẹrẹ orukọ awọn ỌỌNI ILE IFẸ ti wọn ti n jẹ latigba ti ilẹ Yoruba ti wa.

Gẹgẹ bi itan ṣe fi ye wa la si ṣe mu awọn orukọ wọnyii wa fawọn eeyan, paapaa awọn ọmọde asiko yi lati mọ diẹ nipa awọn to ti jẹ Ọọni
 
1 - Oduduwa ni Ọọni akọkọ ti yoo jẹ

2 - Ọsangangan Ọbamakin ni Ọọni keji

3 - Ogun ni orukọ Ọọni kẹta

4 - Ọbalufọnọ Gbogbode lorukọ Ọọni kẹrin

5 - Ọbalufọn Alayemore Oyingbọmẹkun lorukọ Ọọni karun un

6 - Ọranmiyan lorukọ Ọọni kẹfa

7 - Ayetiṣe lorukọ Ọọni keje

8 - Lajamisan lo tẹle e

9 - Lajọdoogun naa tun jẹ

10 - Lafogido lorukọ Ọọni kẹwaa

Awọn to ku ni

11 - Odidimọdẹ Rogbeeṣin


12 - Aworokolọkin

13 - Ẹkun

14 - Ajimuda

15 - Gboonijio

16 - Ọkanlajọsin

17 - Adegbalu

18 - Ọṣinkọla

19 - Ogboruu

20 - Giẹsi

21 - Luwoo (Obinrin)

22 - Lumọbi

23 - Agbedegbẹdẹ

24 - Ọjẹlokunbirin

25 - Lagunja

26 - Larunnka

27 - Ademilu

28 - Ọmọgbogbo

29 - Ajila-Oorun

30 - Adejinlẹ

31 - Ọlọjọ

32 - Okiti

33 - Lugbade

34 - Aribiwọsọ

35 - Ọṣinlade

36 - Adagba

37 - Ojigidiri

38 - Akinmọyẹrọ lo jẹ laarin ọdun 1770 si ọdun 1800

39 - Gbanlarẹ jẹ laarin ọdun 1800 si ọdun 1823

40 - Gbegbaaje jẹ laarin ọdun 1823 si ọdun 1835

41 - Wunmọnije jẹ laarin ọdun 1835 si ọdun 1839

42 - Adegunlẹ Adewẹla jẹ laarin ọdun 1839 si ọdun 1849

43 - Degbinsọkun jẹ laarin ọdun 1849 si ọdun 1878

44 - Orarigba jẹ laarin ọdun 1878 si ọdun 1880

45 - Derin Ologbenla jẹ laarin ọdun 1880 si ọdun 1894, to si jẹ pe jagunjagun nla ni.

46 - Adelekan (Olubuṣe I) jẹ laarin ọdun 1894 si ọdun 1910

47 - Adekọla jẹ laarin ọdun 1910 si ọdun 1910

48 - Ademiluyi (Ajagun) jẹ laarin ọdun 1910 si ọdun 1930, to si jẹ pe oun ni Ọọni akọkọ ti yoo ṣabẹwo siluu Eko, ti awọn amunilẹru igba naa ko le gbojusoke wo oju rẹ nitori agbara to ni.

49 - Adesọji Aderẹmi jẹ laarin ọdun 1930 si ọdun 1980. Oun ni Gomina akọkó ti yoo jẹ ọmọ ilu nilẹ Yoruba, to si tun jẹ minisita akọkọ ti ko ni ipo laarin ọdun 1951 si ọdun 1955.

50 - Okunade Ṣijuwade lo jẹ laarin ọdun 1980 si ọdun 2015.

51 - Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji lo wa lori ipo bayii. Ọdun 2015 ni wọn fi jẹ, ti yoo si jẹ ọba ti yoo pẹ ju lori ipo naa pẹluu ogo Ọlọrun. Ọba Adeyẹye Ogunwusi ni Ọọni to n polongo iṣọkan ilẹ Yoruba kaakiri agbaye, oun si lo mu opin de ba ẹlẹyamẹya nilẹ Yoruba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI