ỌBASANJỌ SỌRỌ LORI IKU ỌMỌ FASORANTI TAWỌN FULANI DARANDARAN PA DANU - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Saturday, July 13, 2019

ỌBASANJỌ SỌRỌ LORI IKU ỌMỌ FASORANTI TAWỌN FULANI DARANDARAN PA DANU

Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti bu ẹnu atẹ lu bawọn afurasi agbebọn kan ti wọn pe ni Fulani Darandaran ṣe yinbọn pa Arabinrin Funkẹ Ọlakunrin to jẹ ọmọ Baba Reuben Fasoranti, olori ẹgbẹ Afẹnifẹre.

Ọjọ Ẹti ana niroyin naa gba igboro kan lẹyin tawọn Fulani Darandaran pa obinrin naa niluu Ondo.

Ọbasanjọ sọ pe ibanujẹ niku ọmọ ọkan lara awọn agba ẹgbẹ Afẹnifẹre jẹ lorilẹ-ede Naijiria, nitori pe asiko ti gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede yi n waaasu alaafia ati iṣọkan lawọn Funlani n waasu ipaniyan ati itajẹsilẹ.

Ninu atẹjade ti oludamọnran Aarẹ ana naa, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi fi sita laipẹ yi lo ti sọ pe a fi kawọn ileeṣẹ eleto aabo lorilẹede yi lo gbọdọ wa awọn ọdaran naa kan, ki wọn si fi wọn jofin to ba yẹ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti jẹ ko ye awọn eeyan pe ẹmi ati dukia pẹluu iṣọkan orilẹede lo yẹ ko jẹ ijọba orilẹede loju, dipo ki wọn maa fi ẹya kan kẹ ẹya min in, eyi ti yoo maa ṣakoba fun idagbasoke orilẹede ẹni.

Bẹẹ lo ba idile Fasoranti kẹdun iku ọmọ wọn, Oloogbe Arabinrin Funkẹ, to si gbadura pe Ọlọrun yoo bu omi itunnu si wọn lọkan.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI