ALAṢẸWO LO PỌ JU NINU AWỌN OṢERE TIATA - IGBANLADOGI JU BỌMBU ỌRỌ SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, August 25, 2019

ALAṢẸWO LO PỌ JU NINU AWỌN OṢERE TIATA - IGBANLADOGI JU BỌMBU ỌRỌ SITA

Gbajugbaja oṣere tiata nni, Oloye Binta Ayọ Mọgaji Odunẹyẹ, tọpọ awọn eeyan mọ si Igbanladogi ti ju bọmbu ọrọ sita, o ni alaṣẹwo lo pọ ju ninu awọn oṣere tiata lorilẹ-ede Naijiria, eyi to jẹ ki wọn maa wọ aṣọ iwọkuwọ lori itage.

O ni bi ki i ba a ṣe pe alaṣẹwo pọmbele ni wọn ni, ko yẹ ki obinrin to ba ni ọkọ gidi nile, to bimọ, to si ni ẹbi rere de idi iṣẹ tiata, ko wa lọ maa ṣi ara rẹ silẹ tabi ṣe afihan ihooho rẹ bi Ọlọrun ṣe daa sita.

Ayọ Mọgaji sọrọ naa lasiko to n kopa lori eto ileeṣẹ tẹlifisan kan ni Naijiria laipẹ yi, to si tu pẹẹrẹ-pẹẹrẹ ọrọ nibẹ.

Binta Mọgaji ni imura eeyan kan nigboro ni nkan ṣe pẹluu idile to ti jade wa ati iwa ọmọluabi to ni, ti yoo si mu ko le ronu jinlẹ pe iru oju wo ni aye fi n wo oun.

O sọ siwaju pe oun korira ki obinrin maa ṣi ara rẹ silẹ lasiko to ba n ṣere itage, lati igba ti oun si ti bẹrẹ ere tiata, aye ko ri ihooho oun ju ejika oun lọ.

Nigba to n dahun ibeere to nii ṣe lori awọn obinrin onitiata to n ṣi ara wọn silẹ lati polowo ọṣẹ tabi ipara to n bo ara, Ayọ Mọgaji salaye pe, ti eeyan ko ba maa polowo sinima onihooho tabi aṣọ ti wọn fi n luwẹ, taa mọ si Bikini, ko si idi kankan fun obinrin lati ṣi ara silẹ, fi polowo ọja kankan tabi fi fa oju awọn onibara rẹ mọra, nitori oju lasan ti to lati polowo ọṣẹ tabi ipara.

O ni iwa ara bibo to wọpọ laarin awọn oṣere tiata lọkunrin ati lobinrin lode iwoyi, ni ko ba oju mu, awokọṣe ṣaa ni awọn jẹ lawujọ, bẹẹ si ni ohun ti eeyan ba ni lọpọlọ lo ja ju, kii se afihan ọyan, idi abi ara bibo.

Igbanladogi to ti n sunmọ ogoji ọdun to bẹrẹ iṣẹ tiata sọ pe ọpọ igba ti oun ba wa ni ẹnu isẹ, ni oun maa n tako abala ere to ba gba koun ṣi ara silẹ tabi wa ni ihooho, bẹẹ ni ẹnu oun kii duro lati gba awọn ọjẹ wẹwẹ akẹẹgbẹ oun nimọran pe ki wọn dẹkun ṣiṣi ara silẹ, tori eyi ko bojumu fun ọmọluabi ati aṣa Yoruba.

Lori awọn sinima to nii ṣe pẹlu afihan ihooho ati iwa jagidi jagan abi lilo ibọn, O ni "Aṣa alaṣa ni a n kọ pẹlu ṣiṣe fiimu onijagidijagan eyi to lodi si aṣa, iṣe ati ohun ajogunba wa lorilẹ-ede Naijiria, idi si ree ti iwa ipanle ṣe n pọ si lorilẹ-ede yii."

Binta Ayọ Mọgaji, lasiko to n fesi lori bi awọn oṣere tiata lode iwoyi ṣe n ri owo nidi iṣẹ naa ju awọn oṣere tiata aye atijọ lọ ninu eyi ti Binta wa, oṣerebinrin naa ni, ohun ti onikaluku fi n jẹkọ, abẹ ewe lo wa.

"Awọn osere tiata ti ẹ ro pe wọn n ri owo pupọ lasiko yii ju asiko tiwa lọ, ṣe inu iṣẹ tiata yii naa lẹ ro pe wọn ti n ri owo pupọ naa lati fi ra awọn ọkọ nla-nla ati awọn ile awoṣifila ti ẹ ro pe wọn ni yii?

"ṣe ẹ ko ro pe 'ẹbun' kọ ni awọn ile ati ọkọ naa, ti kii si i ṣe inu iṣẹ tiata ti wọn n ṣe ni owo ti wọn fi ra awọn ohun meremere yii ti wa?"

Lakotan, o rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lati maa ṣe ere to mu ọgbọn lọwọ, ti yoo ṣe agbelarugẹ aṣa ati iṣe wa, ti yoo si kọ awọn araalu lẹkọ gidi, nitori awokọṣe rere lo yẹ ki awọn onitiata jẹ lawujọ wa.

BBC

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI