NITORI TOYIN AIMAKHU, WỌN SỌRỌ BURUKU SI LIZ ANJỌRIN, LOUN NAA BA DAA PADA FUN WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, August 25, 2019

NITORI TOYIN AIMAKHU, WỌN SỌRỌ BURUKU SI LIZ ANJỌRIN, LOUN NAA BA DAA PADA FUN WỌN

Oju opo Instagram tun ti n gbona jain-jain bayii nitori awọn ololufẹ awọn oṣere tiata obinrin meji nni, Toyin Abraham ati Lizzy Anjọrin, ti wọn n tahun si ara wọn.

Idi ti iṣẹlẹ naa ṣe waye ni bi Lizzy Anjọrin ṣe n ba Ronkẹ Odusanya yọ pe o ku ayọ ọmọ tuntun to bi lẹyin ọjọ diẹ ti iroyin gbalẹ pe Toyin Aimakhu Abraham bi ọmọ tuntun.

Ibeere yii lo bi Lizzy ati awọn ololufẹ rẹ ninu, ti wọn si n beere pada pe igba melo gan ni Toyin funra rẹ yọ pẹlu Lizzy lasiko to ba kede loju opo Instagram rẹ pe oun n ṣe nkan ayọ abi oriire.

Ninu alaye rẹ loju opo Instagram rẹ, Lizzy ni "Se bi emi ni mo dide lati ja fun Toyin Abraham lasiko tawọn eeyan n tabuku rẹ loju opo ayelujara nigba ti iṣẹlẹ ti Ṣeun Ẹgbẹgbẹ waye, amọ titi di asiko yii, Toyin ko ki mi ri ku oriiire lasiko ti mo ba kede pe Ọlọrun ṣe oore nla fun mi."

"Mo ti kede lọjọ Kẹjọ osu Kinni ọdun 2019 pe mo n ṣe iranti mama mi, lọjọ kẹtala ni mo j'oye ẹsin, ọjọ Kẹrinla oṣu Kẹrin ni mo ṣe ọjọ ibi, ti ọmọ mi si ṣe ọjọ ibi tiẹ ni ọjọ Kẹfa oṣu Kẹfa, bẹẹ ni mo ṣi ile tuntun lọjọ Kọkanla oṣu Keje, amọ ko si ibi ti Toyin Abraham ti ba mi yọ rara lasiko awọn ayẹyẹ naa."

Lizzy fi kun un pe lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keje naa ni ẹnikan n dunkoko lati pa oun, ti oun si gbe soju opo Instagram oun, amọ ẹtahoro awọn oṣere lo sọ le ohun ti mo fi sita yii, ti ọpọ wọn ko si fọhun lati ja fun mi, awọn ololufẹ mi ko si ba wọn ja le lori.

O ni bi oun ba n jo lati Oṣu Kinini ọdun wọ oṣu Kejila, o loju oṣere tiata ti yoo sọ pe oun ri oun, ko da a, awọn itan aye oun ti oun kọ lasiko ti oun n ṣile, lee gba omi loju ẹni to ba ti jẹ ori ahun, ṣugbọn sibẹ, diẹ ninu awọn oṣere yii lo da si ọrọ naa.

Lẹyin eyi ni Lizzy, ẹni to ṣẹṣẹ de lati Mẹka (Mecca) de fun iṣẹ Hajj, wa fi epe silẹ fun awọn to ba n tabuku oun pe oun ko ba Toyin Abraham yọ lori ọmọ to bi.

Wayi o, Lizzy wa ṣalaye lẹyin o rẹyin pe oun kuku ki Toyin ku oriire ọmọ tuntun amọ oun ko polowo tabi gbe larugẹ gẹgẹ bi awọn oṣere yoku tii n ṣe e, ni ko jẹ ki ọpọ eeyan mọ pe oun ki Toyin ku ewu ọmọ.

BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI