ARẸWA ỌMỌGE JI TẸLIFIṢAN NLA NI OTẸẸLI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 17, 2019

ARẸWA ỌMỌGE JI TẸLIFIṢAN NLA NI OTẸẸLI

Bi ki i ba a ṣe ọpẹlọpẹ awọn ẹlẹyinju aanu kan ni, boya wọn ki ba ti dana sun ọdọmọbinrin arẹwa kan, ti wọn pe orukọ rẹ ni Laurenta, ẹni ti wọn loo wọ otẹẹli lọ, to si lọ ọ ji ọkan lara awọn amohunmaworan, iyẹn tẹlifiṣan ti wọn lo n lo nibẹ.

Otẹẹli kan ti wọn pe ni Kevleyn, eyi to wa nipinlẹ Delta la gbọ pe Laurenta lọọ ji gbe, ati pe oun pẹluu ọrẹkunrin rẹ kan, tiyẹn ti na papa bora ni wọn jọ gbimọ papọ ji tẹlifiṣan naa gbe.

AWIKONKO gbọ pe ọsẹ kan gbako ni Laurenta ati ọrẹkunrin rẹ fi n gbe ni otẹẹli naa, latari owo ti wọn san sibẹ, ti wọn si n gbadun ara wọn daadaa.

Wọn ni inu baagi nla kan ti wọn n pe ni “Ghana Must Go” ni Laurenta gbe tẹlifiṣan naa pamọ si, asiko to si n gbe e jade ni lawọn ẹṣọ daa duro lati beere nnkan to wa ninu baagi naa, to si lawọn ẹru tawọn gbe debẹ ni.

Bi wọn ṣe gba baagi naa lọwọ ẹ ni tipatipa lo ba bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ. Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn gba wọn nimọnran lati fa Laurenta le awọn ọlọpaa lọwọ.

A ti ẹ gbọ pe ọrẹkunrin Laurenta naa ti ji aṣọ inura, agboorun (umbrella) ati kọkọrọ to jẹ ti otẹẹli naa salọ pẹluu ẹtanjẹ wi pe oun fẹẹ lọ ran nnkan nita. Lẹyin wakati kẹta la gbọ pe Laurenta naa gbe tẹlifiṣan, ṣugbọn ti aṣiri rẹ pada tu sita.

Bẹẹ lawọn kan ti ẹ tun sọ pe Laurenta ti ji miliọnu kan naira din lẹgbẹrun lọna igba (800,000) naira lọwọ ọkunrin kan ti wọn jọ sun laipẹ yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI