O MA ṢE O, KỌMIṢANA PADANU IYA ATI ỌMỌ MEJI LỌJỌ KAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 14, 2019

O MA ṢE O, KỌMIṢANA PADANU IYA ATI ỌMỌ MEJI LỌJỌ KAN ṢOṢO

Titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan, lawọn eeyan ṣi n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si Kọmiṣana fọrọ epo rọbi ati idagbasoke, iyẹn Oil Producing Area Development Commission (ASOPADEC) nipinlẹ Abia, Ọnọrebu Adeile Ekeke.

 
Ọjọ Sannde to kọja ni Ọnọrebu Ekeke padanu iyawo ẹ ati ọmọ meji sinu ijamba mọto lopopona Enugu-Okigwe, lasiko ti wọn n rin irin ajo, ko too di pe ijamba naa waye lojiji.

 
Loju ẹsẹ ni gbogbo wọn ti dagbere faye, to si mu kawọn eeyan kawọ mọri. Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn gbe wọn lọ si mọṣuari, to si jẹ pe ana tii ṣe Tuside ni wọn sin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI