BAALE ILE DA AISIIDI SIYAWO ATAWỌN ỌMỌ RẸ LARA, LO BA NA PAPA BORA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, August 19, 2019

BAALE ILE DA AISIIDI SIYAWO ATAWỌN ỌMỌ RẸ LARA, LO BA NA PAPA BORA

Gbogbo agbegbe Dadumẹ nipinlẹ Katsina lọrọ naa ṣi n ṣe ni kayeefi titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan, lori bi wọn ṣe ni baale ile kan ti wọn loo jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ banki Union da aisiidi si iyawo atawọn ọmọ rẹ lara, to si na papa bora.

 
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ nipa nnkan to ṣokunfa idi ti baale ile naa ti a ko tii mọ orukọ rẹ bayii ṣe gbe igbesẹ naa, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa atawọn eeyan ṣi n wa ọkunrin naa.

 
Bẹẹ la gbọ pe iyawo ọkunrin naa, atawọn ọmọ rẹ ti wa ni ọsibitu ABU, eyi to wa lagbegbe Shika, nibi ti wọn ti n gba itọju.

Bawọn kan ṣe n sọ pe, o ṣee ṣe ki aṣiri ti tu si ọkunrin naa lọwọ pe boya oun kọ lo ni awọn ọmọ naa, ṣugbọn ti a ko ti i le fidi ẹ mulẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI