WỌN LE AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA MẸTALELOGUN KURO NI SAUDI ARABIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 25, 2019

WỌN LE AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA MẸTALELOGUN KURO NI SAUDI ARABIA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, awọn ọmọ Naijiria ti ko din ni mẹtalelogun lo ti wa lorilẹ-ede yi bayii latari ẹsun gbigbe kokeeni ti wọn fi kan wọn lorilẹ-ede Saudi Arabia.

Adeniyi Adebay Zikri, Tunde Ibrahim, Jimh Idhola Lawal, Lolo Babatunde, Sulaiman Tunde, Idris Adewunmi Adepju, Abdul-Raimi Awla Ajibla, Yusuf Makeen Ajiboye, Adam Idris Abubakar, Saka Zakaria, Bila Lawal, Isa Abubakar Adam, Ibrahim Chiroma, Hafis Amosu ati Aliu Muhammad.

Awọn to ku ni: Funmilay mymi Bishi, Mistura Ykini, Amina Ajk Albi, Kuburat Ibrahim, Alaja Olufunk Alalaoe Abdulqadir, Fawsat Balogun Alabi, Aisha Muhammad Amira ati Adebay Zakariya.

Bẹ o ba gbagbe, lai pẹ yi ni wọn dajọ fun ọmọ Naijiria kan, Kudirat Afolabi lori ẹsun gbigbe kokeeni, to si tun jẹ pe ko pẹ lọwọ tun tẹ Saheed obade pẹluu kokeeni ti ko din ni iwọn ẹgbẹrun kan (1,183) giraamu niluu Jeddah.

Awọn ọmọ Najiria mẹtalelogun yi la gbọ pe aarin ọdun 2016 si ọdun 2017 lọwọ tẹ wọn ni papakọ ofurufu King Abdul-Aziz to wa ni Jeddah ati papakọ ofurufu Ọmọba Muhammad bin Abdu- Aziz to wa ni Madinah.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI