Ẹ DẸKUN IWA IBAJẸ LAWUJỌ - ROYAL AMBASSADOR GBAWỌN ARAALU LAMỌNRAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 17, 2019

Ẹ DẸKUN IWA IBAJẸ LAWUJỌ - ROYAL AMBASSADOR GBAWỌN ARAALU LAMỌNRAN


Ẹgbẹ awọn ọdọkunrin ti ṣọọṣi onitẹbọmi, iyẹn Baptist Royal Ambassador, ẹka tipinlẹ Ogun ti pariwo sita fawọn araalu pe ki wọn jawọn ninu awọn iwa adoju ti ni, eyi ti wọn n hu lawọn awujọ, ki alaafia to peye le jọba kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Adari ẹgbẹ naa, Ambassador Sunday Babalọla lo sọrọ naa lọsan onii lasiko to n b'AWIKONKO nibi iwọde ti wọn ṣe lati fi polongo didẹkun awọn iwa ibajẹ lawujọ bii Ifipabanilopọ, Ijinigbẹ, Ipaniyan, ati oniruuru iwa abuku miran an lawujọ.

Nigba to n gba ẹnu adari naa sọrọ, igbakeji adari ẹgbẹ yi, Ambassador Peter Akintẹyẹ sọ pe lati le dẹkun awọn iwa to le pana alaafia ati iṣọkan lorilẹ-ede Naijiria lawọn ṣe pinu lati gbe igbesẹ iwọde ipolongo yi, ati pe eyi kii ṣe akọkọ iru ẹ, ọdọọdun ni wọn n ṣe e.

Oni yatọ si pe awọn alaṣẹ ṣọọṣi naa fọwọ si iwọde yi, to si jẹ pe bawọn ṣe n ṣe e nipinlẹ Ogun naa ni wọn n ṣe e kaakiri orilẹ-ede Naijiria, ijọba naa tun fọwọ si pẹluu, to si n ko ipa ribiribi lawujọ. 

Bakan naa lo tun gba ijọba lamọnran orilẹ-ede yi lamọnran pe ko jẹ ki aabo ẹmi ati dukia awọn araalu jẹ oun logun, nitori pe ilu ti ko ba si aabo, iparun lo n wa, ati pe bi ko ba si awọn eeyan laarin ilu, ahoro lasan ni yoo jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI