LẸYIN ỌDUN MẸẸDOGUN, ỌBASANJỌ FẸẸ PARI IJA LAARIN ILU MEJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, August 19, 2019

LẸYIN ỌDUN MẸẸDOGUN, ỌBASANJỌ FẸẸ PARI IJA LAARIN ILU MEJI

Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lati pari ija laarin ilu nla meji kan to wa labẹ ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, to si jẹ pe ọpọ awọnto ti gbọ ni wọn ti n ṣe sadankata si baba naa lori awọn igbesẹ to fẹẹ gbe naa.

Ọjọbọ tii ṣe Tọside ọsẹ yi ni awọn igbimọ ti wọn yan yoo mu abajade wọn pada lọọ ba Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati le mọ ibi ti iṣẹ naa ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Ati pe orin onigbagbọ nni to sọ pe 'ija d'opin, ogun si tan' lawọn ilu naa yoo mu bọ ẹnu nigba ti Ẹbọra Owu ba yanju aawọ naa, ti alaafia si jọba pada.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọdun 2004 ni wọn ni ija n;a bẹrẹ laarin awọn ilu naa, Itele ati Ayetoro-budo, ta a si gbọ pe ọpọ ẹmi ati dukia ni wọn ti fi ṣofo danu latari ija nla to bẹ silẹ laarin wọn.

Ọjọ Fraide ọsẹ yi lawọn agbaagba ilu mejeeji yi yoo jokoo papọ niwaju Aarẹ tẹlẹri naa, Oloye Ọbasanjọ, ti a si nigbagbọ pe wọn yoo tun jẹun ninu awo kan  naa.

Ki i ṣe pe wọn fẹẹ dee de pari ia naa, bi ko ṣe lati dẹkun wahala ọjọ iwaju ti wọn loo ṣe e ṣe ko bẹ silẹ laarin awọn iran to n bọ lọjọ iwaju, to si ṣee ṣe ko di ogun abẹle nla.

Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ fun AWIKONKO laipẹ yi, agbẹnusọ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi jẹ ko di mimọ pe bi Aarẹ tẹlẹri ṣe n wa iṣọkan ati alaafia kaakiri agbaye, lo mu ko fẹẹ fi opin si aawọn naa.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ fun wa pe Onibudo tiluu Ayetoro-budo, Ọba Adewunmi Adeniji Odutala ti fọkan awọn eeyan balẹ pe ibi rere ni ajọsọ naa yoo fori sọ, nitori pe awọn ti gba lati wa ni irẹpọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI