EYI NI BI WỌN ṢE N FI ORUKỌ IJỌBA LU AWỌN ARAALU NI JIBITI L'ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, August 6, 2019

EYI NI BI WỌN ṢE N FI ORUKỌ IJỌBA LU AWỌN ARAALU NI JIBITI L'ỌYỌ

Awa ko tii bẹrẹ igbanisiṣẹ o - Ijọba

Ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ Gomina Ṣeyi Makinde ti ke gbajare sita fawọn araalu pe ki wọn ṣọra fawọn ti wọn n lo orukọ ijọba lati maa fi gba owo lọwọ wọn, pẹluu ẹtanjẹ pe wọn fẹ ẹ gba wọn siṣẹ.

AWIKONKO gbọ pe awọn kan ni wọn dide lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin pe ijọba ti bẹrẹ igbanisiṣẹ, o si lawọn ọna ti wọn fi n gbawọn eeyan siṣẹ, paapaa lẹka eto ẹkọ nipinlẹ naa.

A gbọ pe fọọmu kan ni wọn gbe jade sita pe awọn yoo mu orukọ awọn ti wọn ba gba fọọmu naa wọle labẹlẹ, eyi ti ko ni jẹ ki wọn ṣe laalaa tabi wahala kankan bi eto naa ba bẹrẹ ni pẹrẹu.

Ko din ni ẹgbẹrun meji la gbọ pe awọn to ti gba fọọmu yi, ta a si gbọ pe bi ọrọ naa ṣe tan kalẹ kaakiri ipinlẹ Ọyọ la gbọ pe o ta si ijọba leti atawọn alaṣẹ eto ẹkọ, ti ẹka SUBEB leti, tawọn naa si tete figbe tan pe ko ri bẹ ẹ rara.

Nigba to n tako ọrọ naa fawọn oniroyin lọjọ Mọnde ana, Alaga ẹgbẹ SUBEB nipinlẹ Ọyọ, Dọkitọ Nureni Adeniran sọ pe iyalẹnu lo jẹ nigba tawọn gbọ pe SUBEB ti bẹrẹ igbanisiṣẹ nipinlẹ Ọyọ, eyi to sọ pe iroyin to jinna si otitọ ọrọ patapata ni.

O ni kawọn to n wa iṣẹ lasiko yi ṣọra daadaa ki wọn ma ba a bọ sọwọ awọn gbajuẹ ti wọn n forukọ ijọba lu awọn eeyan ni jibiti nipa tita fọọmu lati fun wọn niṣẹ labẹ ijọba.

Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe bi asiko ba to fun ijọba lati bẹẹ eto igbanisiṣẹ, ijọba yoo gbe e sori afẹfẹ ati ayelujara fawọn araalu lati mọ, ṣugbọn ni bayii, jibiti lawọn kan fi n lu, nitori naa ki wọn ṣọra lati ma ṣe ko sọwọ wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI