OOGUN ABẸNUGỌNGỌ ṢI N BẸ LỌWỌ MI BII TI ATIJỌ - SUNDAY IGHOHO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 6, 2019

OOGUN ABẸNUGỌNGỌ ṢI N BẸ LỌWỌ MI BII TI ATIJỌ - SUNDAY IGHOHO

Gbajugbaja ajafẹtọ-ọmọniyan nni, to tun jẹ jagunjagun, Oloye Sunda Adeyẹmọ tawọn eeyan tun mọ si Sunday Ighoho ti jẹ ko di mimọ fun ijọba orilẹede Naijiria pe oogun abẹnugọngọ ṣi wa lọwọ oun bi ti atijọ, ko da, toun ṣi le pe ibọn jade lati inu afẹfẹ.

Oloye Sunday Ighoho lo fidi ọrọ naa mulẹ, nigba to n ba ileese iroyin BBC sọrọ niluu Ibadan lọjọ Mọnde ana pe oun ṣetan lati koju awọn daran-daran ti wọn ji awọn eeyan gbe, ti wọn si tun pawọn eeyan danu nilẹ Yoruba, iyẹn bawọn agbaagba atawọn Ọba ilẹ Yoruba ba ṣetan lati tọwọ bọwe adehun pẹluu oun.

O ni yatọ si oun, awọn jagunjagun kan ṣi wa to jẹ pe bijọba ba tọwọ bọwe adehun pẹluu wọn, awọn yoo jọ ṣiṣẹ papọ lati kọju awọn ọdaran ti wọn wọ ilẹ Yoruba wa lati maa ṣọṣẹ buruku.

Bẹẹ lo tun ṣalaye siwaju pe oun ṣetan lati koju oogun to n kogun ja ilẹ Yoruba ki alaafia le tubọ jọba.

Pabambari ẹ ni bo tun ṣe sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe awọn agbaagba kan wa to jẹ pe wọn n jẹ nibi iṣoro eto aabo to n doju kọ ilẹ Yoruba, eyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.

Bakan naa lo tun sọ pe o ṣeni laanu pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ko mọ iṣẹ toun ṣe nigba toun koju ogun Modakẹkẹ ati Ifẹ, ati boun ṣe duro ti Gomina Raṣidi lasiko ijọba rẹ, ti wọn ko si yan oun jẹ lẹyin ogun naa

Lakotan, o sọ pe awọn Fulani ti wọn n ko awọn ọmọ Yoruba si hilahilo ko ni le duro nigba tawọn ba dide lati koju wọn, nitori pe wọn ko ni agbara kankan lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI