GBOGBO AGBAYE ṢI N KI TOYIN AIMAKHU FUN ỌMỌ TUNTUN TO ṢẸṢẸ BI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, August 17, 2019

GBOGBO AGBAYE ṢI N KI TOYIN AIMAKHU FUN ỌMỌ TUNTUN TO ṢẸṢẸ BI

Lọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun yi ni a muu wa fun un yin pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, Oluwatoyin Aimakhu Abraham ti loyun, bẹẹ si ni pe ko ni pẹ ẹ bimọ naa, ati pe ọkan lara awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, Kọlawọle Ajeyẹmi lẹni to loyun fun.

Image may contain: 1 person, smiling
Bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn to ka iroyin naa ni wọn ko tete gbagbọ, ṣugbọn nigba to ya, wọn mọ pe okulowo iroyin la mu wa.

Ni bayii, ati ahesọ, ati gbeborun, ati irọ, gbogbo rẹ lo ti wa a di otitọ bayii, nigba ti Toyin funra rẹ gbe fọto ara rẹ, pẹluu ọmọ tuntun to ṣẹṣẹ bi l'Ọjọru Wẹside ọsẹ yi sori ayelujara pe kawọn eeyan ba oun dupẹ fun ayọ nla naa.

Ẹ WA A GBỌ O, WỌN NI TOYIN AIMAKHU KO NI PẸ Ẹ BIMỌ

Titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn ololufẹ gbajugbaja oṣerebinrin nni, Oluwatoyin Aimakhu lori ọmọ tuntun lanti-lanti to ṣẹṣẹ bi, lẹyin oṣu mẹsan an.

Image may contain: 1 person

Oṣu marun un sẹyin ni Toyin Aimakhu fara pamọ lori itage, to si lọọ fara balẹ tọju ara rẹ, ati oyun to ni fun ọkọ rẹ tuntun, Kọlawọle Ajewọle.

Diẹ re e lara awọn fọto to n kaakiri ori ayelujara. 

Image may contain: 2 people, people smiling, shoes

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI