IDI TI BANKI AGBAYE ṢE FẸẸ FỌWỌSOWỌPỌ PẸLUU IJỌBA IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, August 2, 2019

IDI TI BANKI AGBAYE ṢE FẸẸ FỌWỌSOWỌPỌ PẸLUU IJỌBA IPINLẸ OGUN

Laipẹ yi ni awọn aṣoju alaṣe ile ifowopamọ si agbaye ṣabẹwo wa sipinlẹ Ogun lati wo bi eto ọrọ aje ṣe n lọ si, to si jẹ pe lẹyin awọn ayẹwo ati ifimufinlẹ ti wọn ṣe kaakiri gbogbo ipinlẹ naa ni wọn rii pe ọkan lara awọn ipinlẹ tawọn le kowo le lori ni ipinlẹ Ogun jẹ.

Ẹẹdẹgbẹrun dọla ($900) la gbọ pe banki agbaye naa ya sọtọ lati fi ṣe iranlọwọ fawọn ipinlẹ meloo kan lagbaye fun ilọsiwaju eto ọrọ aje ati idagbasoke, eyi ti orilẹede Naijiria naa wa lara wọn.

Nigba to n sọrọ, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun sọ pe asiko to yẹ gan an lawọn aṣoju yi wa lati gba ipinlẹ naa silẹ lọwọ iparun, eyi to ṣee ṣe ko ṣakoba fawọn olugbe.
 
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ fawọn aṣoju naa lori awọn ọna ti wọn ti le ṣagbatẹru ijọba, to si ni lara wọn ni Ogun State Economic Transformation Project (OGSTEP), Community and Social Development Programme, Saving One Million Lives Programme, Basic Healthcare Provision Fund, State Fiscal Transparency, Accountability and Sustainability Programme, Rural Access and Mobility Programme, Nigeria for Women, ati Private Public Partnership (PPP).

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI