MO FẸẸ DI AARẸ ORILẸEDE NAIJIRIA LẸYIN TI MO BA ṢE GOMINA IPINLẸ KOGI TAN - DINO MẸLAYE SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 2, 2019

MO FẸẸ DI AARẸ ORILẸEDE NAIJIRIA LẸYIN TI MO BA ṢE GOMINA IPINLẸ KOGI TAN - DINO MẸLAYE SỌRỌ

Sẹnetọ Dino Mẹlaye to n ṣoju ẹkun Kogi West nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja ti fi erongba rẹ han sawọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaa awọn ọmọ ipinlẹ Kogi pe lẹyin toun ba kuro nipo gomina ipinlẹ naa, oun tun ṣetan lati di Aarẹ orilẹede Naijiria.

Ijẹta tii ṣe Ọjọru Wẹside ni Sẹnetọ Mẹlaye sọrọ yi nibi ipade to ṣe pẹluu awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Kogi, ko too lọ ṣabẹwo sawọn oniroyin ipinlẹ naa niluu Lọkọja.

Dino Mẹlaye nibi abẹwo naa lo ti tun sọ erongba rẹ lati di gomina ipinlẹ Kogi, to si ni oun ni ipinu lati mu Kogi Tuntun wa fawọn araalu, to si tun jẹ ko ye awọn eeyan pe atẹgun lati di Aarẹ orilẹede yi ni ipo gomina naa yoo jẹ foun lọdun 2027.

Ninu ọrọ Mẹlaye, o sọ pe "Awọn eeyan nipinlẹ Kogi ko ri apẹẹrẹ oṣelu awaarawa, ohun ti an ri lonii ni oṣelu agidi, lati ọwọ awọn alagidi fun awọn alagidi, eyi ti a le ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi ‘greedocracy’.


“Ṣugbọn bi mo da de ipo naa gẹgẹ bi gomina, Ma a kọ Kogi Tuntun nigba ti a ma bẹrẹ sii fi awọn ọgbọn ati agbekalẹ mu idagbasoke ba ipinlẹ Kogi.


“Ijọba mi yoo mu opin de ba ebi ati iṣẹ nipinlẹ yi. Kogi ko ni nnkan ṣe lati di otoṣi. Ma a ṣiṣẹ lori eto agbe ati ọgbin ati eto ayelujara igbalode lati yi igba rere pada fun ipinle yi.


“Mi o ni baba, ẹgbọn, ana abi baba isalẹ lati tukọ erongba mi, ṣugbọn mo ni awọn amuyẹ lati koju oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo. Mi o bẹru ẹnikẹni, mo kan maa n bọwọ fawọn eeyan ni.


"Ẹẹmejidinlogun ọtọọtọ ni wọn ti gbe mi laarin ọdun mẹta, ti mo si ni ẹsun mejila nile ẹjọ, ṣugbọn sibẹ, mo tun ṣi n duro digbi. Mo ni awọn nnkan to yẹ lati gba ipinlẹ yi silẹ lọwọ gomina Yahaya Bello."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI