IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN TẸLẸRI KU LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, July 30, 2019

IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN TẸLẸRI KU LOJIJI

Iyalẹnu lọrọ iku to wọle mu igbakeji gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Alaaji Abdul Rafiu Ogunlẹyẹ ṣi n jẹ fawọn ọmọ ipinlẹ naa, paapaaawọn mọlẹbi rẹ titi dasiko yi.

Bo tilẹ jẹ pe loju ẹsẹ ni wọn ti fi eeru fun eer, erupẹ fun erupẹ, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe aarọ ana tii ṣe ọjọ Aje ni Alaaji Ogunlẹyẹ ki aye pe o digboṣe lẹni ọdun mọkandinlọgọrin (79years) ni ọsibitu kan to wa ni Itele-Ijẹbu.

Fawọn ti ko ba mọ Ogunlẹyẹ, ọdun 1992 si ọdun 1993 ni Alaaji Ogunlẹyẹ fi jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ogun nigba naa, iyẹn Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba.

Ni bayii, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun nigba to n kanminu lori iku Ogunlẹyẹ, o ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi olufọkansin ati aṣiwaju toootọ, to si tun ba mọlẹbi rẹ kẹdun.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI