ỌDUN ILEYA: ỌNỌREBU JIMỌH ỌLAIFA GB'AWỌN ARAALU LAMỌNRAN LORI IFẸ ATI ALAAFIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, August 12, 2019

ỌDUN ILEYA: ỌNỌREBU JIMỌH ỌLAIFA GB'AWỌN ARAALU LAMỌNRAN LORI IFẸ ATI ALAAFIA

Ọkan lara awọn Ọnọrebu pataki lorilẹ-ede Naijiria, Ọnọrebu Jimọh Arẹmu Ọlaifa ti sọ pe ifẹ ati alaafia lo ṣe pataki lati maa fi ba ara wa lo pọ, nitori pe nnkan to le mu ki iṣọkan jọba lorilẹ-ede yi niyẹn.

Ọnọrebu Jimọh Ọlaifa to n ṣoju ẹkun Imẹkọ Afọn si Ẹgbado/Yewa North nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi ranṣẹ si AWIKONKO, eyi to fi ki gbogbo awọn Musulumi jake-jade, paapaa awọn to n ṣoju ku ayẹyẹ ọdun Ileya.

Ninu ọrọ rẹ, eyi ti agbẹnusọ rẹ, Ọmọba Lateef Ogunjọbi fọwọ si lo ti jẹ ko di mimọ pe bawọn Musulumi ba le fi ifẹ ba awọn ẹlẹsin yooku lo pọ, iṣọkan ati alaafia yoo tubọ maa jọba siwaju sii, ti ko si ni i si wahala kankan lawujọ wa, nitori pe nnkan ti iwe mimọ Kuraani fidi ẹ mulẹ niyẹn.

Bẹẹ lo dupẹ lọwọ gbogbo awọn alatilẹyin ẹ patapata, paapaa awọn to dibo yan an lati ṣoju wọn fun bi wọn ṣe n gbaruku tii, ti wọn ko si pada lẹyin rẹ latigba ti wọn ti yan an.

Siwaju sii lo gbadura pe Allah yoo tubọ maa fi ẹmi gigun ati alaafia dawọn lọla lati le jẹ ki wọn ri ọpọlọpọ ọdun laye, to si tun ṣeleri fun wọn pe oun yoo mu gbogbo ileri oun ṣẹ fun wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI