O MA ṢE O: BABA ỌGỌTA ỌDUN FIPA FA IDI ỌMỌDUN MẸRIN YA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉMonday, August 12, 2019

O MA ṢE O: BABA ỌGỌTA ỌDUN FIPA FA IDI ỌMỌDUN MẸRIN YA

Bi ẹ ti n ka iroyin yi, ko tii daju pe ẹwọn kọ ni Baba agbaaya ẹni ọgọta ọdun kan, Clement Ikechukwu Ogenyi yoo ti lo eyi to ku ninu igbesi aye rẹ, pẹluu bi aṣiri ẹ ṣe tu pe o fipa ja ibale ọmọdun mẹerin kan ta a forukọ bo laṣiri.

Agbegbe Otukpo nipinlẹ Benue niṣẹlẹ naa ti waye lopin ọsẹ to kọja yi, to si jẹ pe diẹ loku kawọn eeyan dana sun un nita gbanga.

A gbọ pe oogun oyinbo kan ti wọn pe ni Vitamin C ni Iya ọmọ naa ran an pe ko lọ ọ ra wa, ko too di pe baba agba radarada naa fọgbọn tan an wọle, to si fipa ja ibale ẹ.

Ki i ṣe pe aṣiri dee de tu sita, bi ko ṣe bi wọn ṣe lọmọ naa rin de ile pada lo mu ifura dani fun iya rẹ, to si yẹ abẹ ọmọ rẹ wo. Ariwo 'Ẹ gba mi o' ni wọn lobinrin naa mu bọ ẹnu, ko too di pe wọn lọọ ka Ikechukwu mọle.

Ogun idile to fẹẹ foun ṣẹlẹya ita gbangba ni wọn lo n tẹnu mọ pe o ti oun de ọdọ ọmọ naa, to si jẹ pe nigba toun ṣe e tan loju oun ṣẹṣẹ la

Awọn araadugbo ni wọn sọ pe ki wọn lọ ọ fa le awọn ọlọpaa lọwọ, ki wọn ma ba a jẹbi nipa ṣiṣe idajọ lọwọ ara wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI