ABIỌDUN POKUNSO L'ABẸOKUTA NITORI IYAWO Ẹ N YAN AALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 15, 2019

ABIỌDUN POKUNSO L'ABẸOKUTA NITORI IYAWO Ẹ N YAN AALE

Gbogbo adugbo kan ti wọn n pe ni Abẹokuta niluu Alagbado ipinlẹ Eko lo fẹẹ le daru lọjọ Tuside to kọja yi nigba ti wọn sọ pe baale ile kan, Abiọdun Tijani deede gba ẹmi ara rẹ latari ẹsun ti wọn loo fi kan iyawo rẹ pe o n yan aale, o si n fi ọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu.
 
AWIKONKO gbọ pe ọdun kejila re e ti Abiọdun, ọmọ bibi adugbọ Agọ-Ika niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun to yan iṣẹ gbẹnagbẹna laayo ti n fẹ iyawọ rẹ, ti wọn si bi ọmọ kan ṣoṣo ti wọn pe orukọ rẹ ni Wasiu.

Ilu Abẹokuta la gbọ pe awọn mejeeji n gbe tẹlẹ, ko too di pe iyawo Abiọdun ti wọn lo n ta worobo ni Toll Gate atijọ l'Ọta ko ẹru rẹ lọ siluu Ekoo lati lọ maa gbe, iyẹn lọdun mẹsan-an sẹyin.

Ọdun to kọja yi ni wọn sọ pe Abiọdun ko ẹru rẹ lọ siluu Ekoo lati lọ ba iyawo ati ọmọ rẹ, ti wọn si jọ n gbe papọ gẹgẹ lọkọ-laya pada, nitori ta a gbọ pe gbogbo akitiyan Abiọdun lati jẹ kiyawo ẹ maa ko bọ wa ba oun niluu Abẹokuta lo ja si pabo.
 
Wọn ni laipẹ yi Abiọdun fura si iyawo ẹ pe o n fi ọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu, ti ija si waye laarin awọn mejeeji, ko da, ti wọn lawọn eeyan ba wọn da si, ṣugbọn ti wọn ni ara Abiọdun ko gba.

Gbogbo akitiyan Abiọdun gẹgẹ bi awọn to gbe ọrọ naa si AWIKONKO leti ṣe sọ lati jẹ ki iyawo ẹ jawo ninu iwa naa ni wọn loo ja si pabo, paapaa nigba ti wọn lo tun n fi ẹtọ rẹ nipa ibalopọ dun un, eyi gan an la gbọ pe o mu aye su Abiọdun.

Nigba tiṣẹlẹ naa maa waye, wọn ni Abiọdun ati ọmọ rẹ, Wasiu ni wọn jọ wa ninu ile lọjọ naa, igba to rii pe ọmọ naa ko jade, ni wọn loo fọgbọn tan an jade pe ko lọ ge irun ori rẹ, to si fun ni owo ti yoo fi ge irun rẹ.

AWIKONKO gbọ pe nigba ti ọmọ naa maa fi pada wọle, kayeefi lo jẹ pe ibi ti baba rẹ ti n mi jolonjolo lori oke lo ti ba a, loju ẹsẹ lo si ti pariwo sita. Ki oloju to o ṣẹ ẹ, ero adugbo ti pe sibẹ.

Ko pẹ ti wọn fi ranṣẹ sawọn ọlọpaa agbegbe Alagbado lati wa a fidi ẹ mulẹ. Awọn ọlọpaa naa la gbọ pe wọn pada sọ oku Abiọdun kalẹ, ti wọn si gbe e lọ si mọṣuari fun ayẹwo.
 
Wasiu, nigba to n fomije sọrọ sọ pe "Ọjọ Aje Mọnde ni baba mi ti jade kuro nile, to si jẹ pe ọjọ Tuside tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni wọn too pade sile. Nigba ti wọn maa de, mama mi ti jade, emi nikan ni mo wa nile. Bi wọn ṣe de, wọn jokoo diẹ, ko si pẹ ni wọn fun lowo pe ki n lọ ge irun ori mi.

"Nigba ti mo maa pada wọle lati ibi ti mo ti lọọ ge irun ori mi, o jẹ iyalẹnu fun mi pe oku wọn ni mp ba loke to n mi jolonjolo. Ẹru ba mi, ṣe ni mo sare jade lati lọọ pe awọn araale lati wa a wo o. Wọn ko ba mi sọ nnkankan tẹlẹ, mi o si le sọ nnkan to fa ti wọn fi gbe igbesẹ lati pa ara wọn.
 
"Baba mi ko ni baba mọ, ṣugbọn iya wọn ṣi wa laye, ilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun ni wọn n gbe. Ọmọ bibi Agọ-Ika niluu Abẹokuta ni baba mi. Ọrọ naa toju su mi gidi gan an ni."
 
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ boya awọn ọlọpaa ti mu obinrin naa, ṣugbọn ohun tawọn eeyan n sọ ni pe iṣẹlẹ naa kii ṣoju lasan, o lọwọ aye ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI