ỌWỌ EFCC TUN TẸ ỌMỌ YAHOO MỌKANLA NI SAPẸLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 15, 2019

ỌWỌ EFCC TUN TẸ ỌMỌ YAHOO MỌKANLA NI SAPẸLẸ

Laarọ ọjọ Abamẹta Satide ana la gbọ pe ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC tẹ awọ gendekunrin mọkanla kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ.

Ilu Sapẹlẹ nipinlẹ Delta la gbọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ EFCC ti ẹkun Benin ti lọọ ko awọn eeyan, lẹyin ti wọn lawọn kan ta awọn EFCC naa lolobo, ta a si gbọ pe fun ọpọlọpọ wakati lawọn eeyan fi fẹhonu han lori iwa tawọn EFCC hu naa.

Ọmọmua Victor, Demi Johnson, Agufure Godstime, Agboroko Precious, Anthony Ọmọnọmọ, Onskharoma Julius, Freeborn Efe, Akama Precious, Tagbajiemi Promise George Raphael ati Stanley Agabiri lawọn tọwọ tẹ naa.

Lara awọn nnkan ta a gbọ pe wọn gba lọwọ wọn ni ẹrọ Kọmputa alagbeeka, mọto bọginni ti Mercedes-Benz, foonu loriṣiriṣi atawọn irinṣẹ min in ti wọn n lo.

Wọn lawọn eeyan naa ti jẹwọ pe o ti pẹ tawọn ti wa nidi iṣẹ naa, bẹẹ la gbọ pe wọn ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI