AṢIRI BI BỌBRISKI ṢE NA PAPA BORA LỌJỌ AYẸYẸ ỌJỌ-IBI Ẹ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, September 4, 2019

AṢIRI BI BỌBRISKI ṢE NA PAPA BORA LỌJỌ AYẸYẸ ỌJỌ-IBI Ẹ L'EKOO

Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lọjọ Satide ọsẹ to kọja yi nile itura Pearls Gardens to wa ni Lekki Phase 1 nigba tawọn ọlọpaa yawọ 'bẹ lati mu ọdọmọkunrin ti orukọ rẹ n jẹ Idris Okunẹyẹ,ẹni ti gbogbo aye mọ Bobrisky latari ẹnu to fi kọ pe ko sẹni to le mu oun.

Ọjọ naa gangan ni ayajọ ayẹyẹ ọjọ ibi Bobrisky to n ṣebi obinrin lorilẹ-ede Naijiria, tawọn eeyan si n bu ẹnu atẹ lu iwa rẹ loriṣiriṣi, paapaa nigba tawọn kan fi fẹ maa ri i gẹgẹ bi awokọṣe wọn, ṣugbọn tawọn kan n sọ pe o ye kijọba tete wa nnkan ṣe si ọrọ ẹ ko too pẹ ju.
AWIKONKO gbọ pe ọga agba nileeṣẹ ijọba to n ri si sọrọ Aṣa ati Iṣẹṣe, Ọtunba  Oluṣẹgun Runṣewe lẹni ti Bobrisky yaju si, ki oloju si too ṣẹ ẹ, ṣe ni nnkan daru mọ ọn lọwọ patapata, tọrọ si di bi bami-in mọ ọn lọwọ bayii.

Lọjọ Satide na gan-an ni Bobrisky loun yoo patẹ ariya nla, nibi to ti fẹ ẹ ko awọn tiẹ jọ lati ṣayẹyẹ ọjọ-ibi ẹ fun wọn, ṣugbọn bo ti ṣe n pete ariya naa lọwọ, bẹẹ lawọn ọlọpaa n ṣọ ọ, bo si ti ṣe ku diẹ ki wọn bẹrẹ inawo ọhun lawọn agbofinro yade 'bẹ lati da nnkan ru mọ wọn lọwọ.

B'iroyin naa ṣe kan si Bobrisky nibi to wa, la gbọ pe oun naa ba ẹsẹ rẹ sọrọ, to na papa bora, tawọn eeyan ko si mọ ibi to gba salọ lọjọ naa.

Bẹ o ba gbagbe, ko too di asiko yii ni Bobrisky ti fẹnukọ, nibi to ti n halẹ wi pe ko si ohun kan bayii ti Ọtunba Oluṣẹgun Runṣewe le ṣe foun, nitori pe awọn to ju u lọ daadaa lẹnu iṣẹ ijọba loun n ba tayo, ti ọrọ ba di pe eeyan n mọ eeyan lawujọ.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹluu akọroyin oloyinbo kan ni Ọtunba Runṣewe ti bu ẹnu atẹ lu iwa ati iṣesi Bobrisky. O ni, asiko ti to bayii fun ijọba lati tako iwa idojutini ti Bobrisky n ko ba awujọ Naijiria kaakiri agbaye.

O ni, “Bobrisky ti ẹ n wo yẹn, idojuti nla gbaa lo jẹ fun orilẹ-ede wa. Ohun ti awọn eeyan mọ ọn mọ tẹlẹ ni pe, awon ipara gbigbona tawọn eeyan fi n bora lo kọkọ fi bẹrẹ, nigba to ya lo di pe, oun naa wa ọgbọn da si aya ẹ, ti oun naa di ẹni to ni omu meji bii ti obinrin, bẹẹ lo tun yọ idi bọmbọ bii obinrin, to n wa fi oṣi ṣe ayọ kaakiri.

"Ti Bobrisky ba n ṣe iru iwa idojuti yii lawujọ, to fi n pawo, bawo la ṣe le ba awọn ọdọ orilẹ-ede yii sọrọ lati ma ṣe tẹle irufẹ iwa bẹẹ? Loootọ ni Bobrisky ni eto, ṣugbọn iru eto yii ki i ṣe ohun to ba oju mu lawujọ Naijiria.

“Ki i ṣe oun nikan lo n hu iru wa yii, iru ẹ pọ daadaa, ṣugbọn ki i ṣe orilẹ-ede yii ni wọn wa, kaakiri lawọn orilẹ-ede mi-in niru wọn wa. Ti a ba si kọ, ti a ko gbe igbesẹ to nipọn lori ọrọ Bobrisky, ko sigba ti ko ni ko awọn eeyan kan jọ, ti wọn a maa jẹ iru aye ijẹkujẹ yii kiri, eyi to ṣee ṣe ko gbilẹ ju bi a ṣe lero lọ.

“Ibanujẹ nla ni abajade iru iwa idojuti yii yoo si jẹ, abi nigba ti awọn obi ba n pokunso, ti wọn n gbe majele jẹ nigba ti ọmọ ti wọn fi gbogbo ọjọ aye tọju ba n ṣe bii Bobrisky, ti ọkunrin n ṣe bii obinrin kaakiri.

“Ohun to wa nilẹ yii, ki i ṣe ere tabi awada, ohun aburu gbaa ni Bobrisky fẹ ẹ bẹrẹ lorilẹ-ede yii, bẹẹ la gbọdọ gbogun ti i, ko too d'ohun ti apa ko ni i ka mọ, ki a le ni ọjọ ọla to dara.

Ọtunba Runṣewe

"Iṣẹ ti mo gba ni, lati mojuto igbelarugẹ Aṣa wa ati iṣe ọmọluabi lorilẹ-ede yii. Bẹẹ ni yoo jẹ ohun to bu ni ku, ti mo ba dakẹ lai fọhun si oṣi ti ọdọmọkunrin yii n ṣe, to sọ pe oun n yọ kiri. Ati pe ta o ba tete gbe igbesẹ, ko s'igba ti awọn ọmọkunrin naa ko ni maa gbe igba aṣewo lẹgbẹẹ titi.

"Laipẹ yii ni ọmọ orilẹ-ede yii kan; gbajumọ nla l'ẹni ti mo n wii, o ṣabẹwo si ọmọ ẹ niluu oyinbo, iyanu nla lo jẹ fun un nigba to ri i pe ibaṣepọ ọkunrin si ọkunrin l'ọmọ oun n ṣe niluu oyinbo. Iṣẹlẹ to ri yii ba a lojiji, loju ẹsẹ laisan kọluu, ori kẹkẹ ni wọn gbe e si pada si Naijiria nibi.

"Gẹgẹ bi ipo mi lorilẹ-ede yii, awọn ẹri kan wa daadaa ti mo ni, eyi to fi han wi pe awọn ọmọ kekeeke mẹtalelogun kan ti wa, to jẹ pe niṣe ni wọn n ṣe bii Bobrisky, eyi bani ninu jẹ pupọ, bẹẹ la ṣetan lati f'opin siru awọn iwa ọdaran yii.”

Bi Ọtunba Oluṣẹgun Runṣewe ti sọrọ yii tan ni Bobrisky naa da a lohun, ohun to si sọ ree;

“Mo gbọ pe ẹnikan to wa ninu ijọba n sọ nipa mi, ẹ ba mi sọ fun un daadaa wi pe mo n duro de o, o maa too ye e wi pe, awọn to ju u lọ daadaa ni mo maa n ba ṣe lagbo ijọba. Ki i ṣe iru oun yẹn, o kere. O jọ pe ẹni yẹn gan-an ko mọ ohun to ku mọ, pẹlu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria yii to jẹ pe ọrọ emi Bobrisky lo wa ku fun un lati tẹ lewọ bii igba, ko si wahala o, mo tun fi n lorukọ si i ni.”

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Satide ọsẹ to kọja yii ni Bobrisky di ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ariwo to si n pa ni pe, oun yoo mi gbogbo ilu Eko titi lọjọ Satide ati Sande, ṣugbọn ti nnkan pada daru mọn ọn lọwọ.

Magasinni Alore

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI