EYI NI BI PASITỌ ṢE GBÉ MAJELE JẸ L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, September 3, 2019

EYI NI BI PASITỌ ṢE GBÉ MAJELE JẸ L'OGUN

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta Gbogbo adugbo Atala to wa niluu Mowe lo fẹẹ le daru lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi nigba ti wọn ni Pasitọ kan to gbajumọ daadaa lagbegbe naa, iyẹn Tunde gbe majele jẹ, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

A gbọ pe awọn kan ni wọn lu Tunde ti wọn ni ọkan lara awọn pasitọ ṣọọṣi Deeper Life ni jibiti owo ti ko din lẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (600,000) naira, to si jẹ pe itiju gbese naa lo muu pinu lati gbẹmi ara rẹ lojiji.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ fi ye wa pe ajọ ni Tunde n gba kaakiri lẹyin to padanu iṣẹ ẹ lọdun bii meji sẹyin, to si jẹ pe ko sẹni ti mọ ni gbogbo ibi to n gba ajọ naa de.

Ohun to ti ẹ n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi ni pe Tunde ti ran iyawo ẹ jade lọjọ naa, ṣugbọn nigba tiyawo naa maa fi pada wọle, okọ ẹ lo ba nilẹ nibi to ti n japoro, eyi lo muu sare pe awọn ara adugbo lati ran an lọwọ gbe e lọ si ọsibitu kan to wa nitosi wọn.

Oju ọna la gbọ pe Tunde ti dagbere faye, ọsibitu ni wọn si ti jẹ ko di mimọ fun wọn pe oku ni wọn gbe wa fawọn, ati pe aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ, tori to ti rin ihoho wọja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI