ÌLÚ KAN, ỌBA MÁRÙN-ÚN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 14, 2019

ÌLÚ KAN, ỌBA MÁRÙN-ÚN

Nínú iṣẹ̀dálẹ̀ àti ìdásílẹ̀ ìtàn ilẹ̀ Yorùbá, ọ̀kan pàtàkì ni ẹ̀yà Ẹ̀gbá jẹ́. Ẹ̀yà kan ni tó jẹ́ pé púpọ̀ nínú àdámọ́ wọn kò sí nínú àwọn ẹ̀yà tó kù nílẹ̀ Yorùbá tí Olódùmarè sì fi ẹbùn ìfẹ́ àti iṣọ̀kan jíǹkí wọn.
 
Yàtọ̀ sá àṣà àti ìṣe tí a mọ̀ wọ́n mọ́, ìwà ọmọlúàbí, ìrẹ̀lẹ̀ àti ìkónimọ́ra jẹ́ kí ẹ̀yà yìí di ìlú-mọ̀-ọ́-ká káàkiri àgbánlá ayé. A rí eléyìí níbi ètò iṣèjọba, ètò ọrọ̀ ajé, ètò amúlùúdùn, ètò òṣèlú, ẹ̀sìn àti àwọn àṣà mìíràn tí a fi lè gbé oríyìn fún ọmọniyàn.
Níbi ètò oṣèlú, Ẹ̀gbá ló wà lókè títí di àsìkò yìí, nítorí pé àwọn bíi Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, Olóyè Ernest Ṣónẹ́kàn, Olóyè Olúsẹ́gun Ọ̀ṣọbà ni kò ṣée fọwọ́ rọ́ tì sẹ́yìn. Bákan náà níbi ètò ọ̀rọ̀ ajé, àwọn bíi Olóògbé Moshood Káṣìmaàwó Abíọ́lá ni wọ́n ń wà lókè.
Níbi ètò amúlùúdùn, Ẹ̀gbá náà lẹ máa rí níwájú nítorí pé àwọn bíi Olóògbé Akin Ògúngbè, Olóògbé Dúró Ládiípọ̀ atàwọn mìíràn ni wọn sọ ètò amúlùúdùn dirọ̀rùn. Bẹ́ẹ̀ níbi ètò ẹ̀kọ́, kò tíì sí ìlú kan nínú àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí wọ́n lè figagbága pẹ̀lú àwọn ọmọ Ẹ̀gbá tí wọ́n ti wà lókè atàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde bọ̀ bíi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyinká tá gba àmì ẹ̀yẹ àgbáyé, èyí tí ẹnikẹ́ni kò tíì gba irú ẹ̀ rí nílẹ̀ Yorùbá, pàápàá lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Ọmọba Bọ́lá Ajíbọ́la tó jẹ́ olùdájọ́ àgbà nílé ẹjọ́ àgbáyé tí kò tún tíì sí irú ẹ̀ dàsìkò yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, Débọ̀ Alébíoṣù, Àlàgbà J.F Ọdúnjọ̀, Amọ̀fin Bọ́lá Ṣólàńkẹ́ tó jẹ́ ẹni tó kọ́kọ́ gba oyè ìmọ̀ òfin lórìlẹ̀-èdè Nàíjíríà, Olòógbé Títílayọ̀ Ransom Kuti tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ wa ọkọ̀ nílẹ̀ Yorùbá àti lórílẹ̀-ède Nàíjíríà lápapọ̀.
A kò lè sọ̀rọ̀ ètò amúlùúdùn tán láì mẹ́nuba àwọn òǹkọrin bíi Olóògbé Fẹlá Aníkúlápó, Olóyè Ebenezer Obey, Àyìnlá Ọmọwúrà, Yusuf Ọlátúnjí, Ṣínà Peters, tó fi dé orí Alhaji Ṣẹ̀fìú Àlàó wọ́n ṣì ń ṣe iṣẹ́ ribiribi láwùjọ wa di àsìkò yìí.
Bákan náà nínú ètò eré ìdárayá, àwọn ọmọ Ẹ̀gbá ni wọ́n ń lékè. A ò lè sọ̀rọ̀ láì mẹ́nuba àwọn bíi Múdàṣírù Lawal, Ṣẹ́gun Ọdẹ́gbàmí.
Nínú àwọn nǹkan tó ń mú kí ìlú Ẹ̀gbá tayọ ni ti ìmúgbòòrò ẹ̀yà náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka máráàrún tí àwọn Ọba aládé márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jẹ́ olórí fún. Àwọn ẹ̀ka náà ni Ẹ̀gbá Aké, Ẹ̀gbá Òwu, Ẹ̀gbá Àgùrà, Ẹ̀gbá Ọkè-Ọ̀nà àti Ìbarà.
ORI OKE OLUMỌ
Ẹ̀GBÁ AKÉ tó ní àwọn àdúgbò bíi: Ìtẹsi, Ìkọpa, Ìbaràpá, Àdátán, Aṣérò, Isàlẹ̀-Aké, Ìjẹmọ̀, Ìtokò, Ìpóró-Aké, Òkè Ejìgbò, Èrúnwọ̀n, Ijàyè, Ọbáńtokò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní Ọbá Aláké tó tún jẹ́ olórí àwọn ọba pátápátá ní Ìpínlẹ̀ Ògùn báyìí jẹ́ olórí fún. Aláké ni wọ́n ń pe orúkọ Ọba wọn.
Àwọn Ọba ti wọ́n ti jẹ ni: Ọba Òkúkẹ́nù tó jẹ láàárín ọdún 1854 sí ọdún 1862; Ọba Adémọ́lá (I) tó jẹ láàárín ọdún 1869 sí ọdún 1877; Ọba Oyèkan tó jẹ láàárín ọdún 1879 sí ọdún 1881; Ọba Olúwájí tó jẹ láàárín ọdún 1885 sí ọdún 1889; Ọba Ọṣokalu tó jẹ láàárín ọdún 1891 sí ọdún 1898; Ọba Gbádébọ̀ (I) tó jẹ láàárín ọdún 1898 sí ọdún 1920.
Àwọn mìíràn ni Ọba Ládàpọ̀ Adémọ́lá (II) tó jẹ láàárín ọdún 1920 sí ọdun 1962; Ọba Samuel Adéṣínà Gbádébọ̀ (II) tó jẹ láàárín ọdún 1963 sí ọdún 1971; Ọba Mofọ́lọ́runṣọ́ Oyèbádé Lípèdé tó jẹ láàárín ọdún 1972 sí ọdún 2005, tó fi wá dé orí Ọba Adédọ̀tun Àrẹ̀mú Gbádébọ̀ tó jẹ lọ́dún 2005 títí di asìkò yìí.
Ẹ̀GBÁ ÒWU: Lẹ́yìn náà ni Ẹ̀gbá Òwu tó ní àwọn àdúgbò bíi: Tótoró, Akin-Olúgbadé, Òkè Ṣòkòrì, Ìta-Ẹ̀kọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olówu tilùú Òwu ni wọ́n ń pe Kábíyèsí wọn.
Àwọn Ọba tí wọ́n ti jẹ ni: Ọba Pawu ni Ọba tó jẹ láàárín ọdún 1855 sí ọdún 1867, Ọba Adéfọwọ́tẹ̀ tó jẹ láàárín ọdún 1869 sí ọdún 1872, Ọba Adérìnmóyè tó jẹ ní ọdún 1873 sí ọdún 1873 sí ọdún 1890, Ọba Owookade tó jẹ láàárín ọdún 1893 sí ọdún 1905, Ọba Adésùnmbọ̀ Dosùnmú Amọ́roro (I) tó jẹ láàárín 1918 sí ọdún 1924.
Àwọn mìíràn ni Adésínà tó jẹ láàárín 1924 sí ọdún 1936, Ọba Adéláni gbogboadé Otileta (IV) 1938 sí 1946, Ọba Salami Adéwùnmí Ajíbọ́lá Gbádélà (II) 1949 sí ọdún 1972, Ọba Adéwálé Oyegbadé tó jẹ láàárìn 1975 sí ọdún 1980 títí tó fi dé orí Ọba Olúsànyà Adégbóyèga Dòsùnmú Amọ́roro (II) tó jẹ lọ́dún 2005 títí di òní yìí.
Ẹ̀GBÁ ÀGÙRÀ: A tún ní Ẹ̀gbá Àgùrà tóun náà ní àwọn àdúgbò bíi: Òkè-Ìdó, Àgọ́-Ìkà, Ìta-Ìká, Ìkerèkú, Adédọ̀tun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Orúkọ Ọba wọn ni Ẹ̀gbá Gbágùrá.
Àwọn ọba tó ti jẹ ní: Ọba Jámólú tó jẹ láàárín 1870 sí ọdún 1877, Ọba Ìjàadé tó jé láàárín ọdún 1878 sí ọdún 1893, Ọba Olúbùnmi tó jé láàárín ọdún 1897 sí ọdún 1910, Ọba Abọ́ládé tó jẹ láàárín ọdún 1910 sí ọdún 1915, Ọba Adéọ̀sun (I) tó jẹ láàárín 1915 sí ọdún 1936, Ọba Bakare Bábaṣolá Ọlálokò Sóbẹ́kùn (I) tó jẹ láàárín ọdún 1937 sí ọdún 1960.
Àwọn mìíràn ni Ọba Raufu Adéọ̀sun (II) tó jẹ láàárín ọdún 1961 sí ọdún 1978, Ọba Halidu Adédayọ̀ Ọlálokò Ṣóbẹ́kùn (II) tó jẹ láàárín ọdún 1980 sí ọdún 2018.
Ọba Abdul-Subur Bakare tó jẹ lọ́dún 2018 ló wà lórí oyè báyìí.
ÒKÈ-Ọ̀NÀ tún jẹ́ ìlú mìíràn lára àwọn ẹ̀yà Ẹ̀gbá. Lára àwọn àdúgbò tó wà lábẹ́ Òkè-Ọ̀nà ni Ṣàpọ́n, Àgọ́-Òkò, Ìjeùn-Titun, Òkè-Ìjeùn, Ìṣábọ̀, Kútọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀ṣilẹ̀ ni orúkọ Ọba wọn.
Àwọn ọba tó ti jẹ ni: Ọba Kárunwí (I) tó jẹ ní ọdún 1897 sí ọdún 1899, Ọba Sànyàolú Adébáre (I) tó jẹ láàárín 1900 sí ọdún 1902, Ọba David Ṣókúnbi Kárunwí (II) tó jẹ láàárín ọdún 1904 sí ọdún 1918, Ọba Suberu Adédàmọ́lá (I) tó jẹ láàárín ọdún 1918 sí ọdún 1932, Ọba Yesufu Adédọ̀tun Idòwú tó jẹ láàárín 1932 sí ọdún 1934, Ọba Emmanuel Ṣóbáyọ̀ Adébáre (II) tó je láàárín 1934 sí ọdún 1944, Ọba Alimi Adédìran Adédàmọ́lá (II) tó jẹ láàárín ọdún 1951 sí ọdún 1988.
Ọba (Dr.) Adédàpọ̀ Adéwálé Tẹ́júosó Kárunwí (III) ló wà lórí oyè lọ́wọ́ báyìí,
ÌBARÀ: Ìlú mìíràn tún ni Ìbarà jẹ́ nínú àwọn ìlú tó wà lábẹ́ ẹ̀yà Ẹ̀gbá, lára àwọn àdúgbò tó wà lábẹ́ ni Omídá, Òkè-Ìléwó, Oníkókò, Panṣẹ́kẹ́, Olómore àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Olúbarà ni orúkọ Ọba aláde wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI