NITORI AYẸYẸ ỌDUN IṢU, WỌN LE KABIYESI KURO L'AAFIN L'ONDO, BẸẸ NI WỌN LU OLORI L'ALUBAMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, September 14, 2019

NITORI AYẸYẸ ỌDUN IṢU, WỌN LE KABIYESI KURO L'AAFIN L'ONDO, BẸẸ NI WỌN LU OLORI L'ALUBAMI

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ara ko tii rokun, bẹẹ ni ara ko tii ro adiẹ niluu Ilara Mọkin to wa nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo lori bi wọn ṣe lawọn ọdọ agbegbe naa doju ija kọ Ọba wọn, Ọba Aderẹmi Adefẹhinti, ti wọn si lu oun ati olori ẹ nilukulu.

Ni bayii, AWIKONKO gbọ pe Kabiyesi naa ti na papa bora lati doola ẹmi oun atawọn mọlẹbi ẹ l'Aafin.

Bo tilẹ jẹ pe wahala naa ti wa nilẹ tipẹ, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe ko si nnkan meji to n da wahala silẹ niluu naa, bi ko ṣe bi wọn ṣe sọ pe Kabiyesi naa, Ọba Adefẹhinti ṣe kẹhin si iṣẹṣe, paapaa awọn ọdun abalaye ilu naa wahala nla kan ti wọn.

Ọdun 1998 la gbọ pe wọn fi Ọba Aderẹmi Adefẹhinti jẹ niluu Ilara Mokin. Ko pẹ si asiko ti wọn fi Kabiyesi j'ọba naa la gbọ pe o kede pe oun ko nii lọwọ si eyikeyi nnkan to ba jẹ mọ iṣẹṣe mọ, tori pe o lodi si ẹsin oun tii ṣe Kristẹẹni.

Gbogbo eto tabi ayẹyẹ ọlọdọọdun ti wọn ni wọn n ṣe niluu naa ni wọn sọ pe Kabiyesi kii yọju si, paapaa awọn iṣẹṣe to nii ṣe pẹluu olori iluu tii ṣe Kabiyesi. Eyi ni wọn si lo n bi awọn kan ninu, ti wọn si n sọ pe Kabiyesi ti gbabọdi fun.
  
Laipẹ yi ni wọn sọ pe wọn ṣe ọkan lara awọn ayẹyẹ iṣẹmbaye ọlọdọọdun wọn, iyẹn ọdun Iṣu, ti wọn si lawọn kan ti pa aroko si Kabiyesi pe bi ko ba fi yọju sibi ayẹyẹ naa, awọn yoo gbena woju ẹ, tawọn yoo si da seria fun un.

Si iyalẹnu wọn, wọn ni Kabiyesi naa kọ lati yọju sibẹ, idi ni yii ti wọn lawọn ọdọ iluu ti iwa Kabiyesi naa ko tẹ lọrun fi gba Aafin ẹ lọ, ti wọn si lọọ da wahala nla silẹ, ti wọn bẹrẹ sii ju okuta lu Aafin naa.

Bi wahala naa ṣe n lọ ni wọn loo mu kawọn ẹṣọ alaabo fọgbọn gba ẹyinkule gbe Kabiyesi salọ fun, lati ma baa ṣe e leṣe tabi pa a danu, ṣugbọn sibẹ ti wọn loo fara gba okuta.

Olori Kabiyesi nibi ti wọn loun naa ti yọju lati dawọn wahala naa duro ni wọn ti koju ẹ, ti wọn dana iya fun un, awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn sare debẹ lati gba olori naa silẹ, ti wọn si gbe e lọ si ọsibitu kan ti wọn ko darukọ, nibi to ti n gba itọju lọwọ bayii.

AWIKONKO gbọ pe ohun tawọn ọdọ ilu naa n sọ bayii ni pe ki kabiyesi naa fi itẹ silẹ fun wọn lati yan ẹlọmin in, nitori pe ẹni ti ko ba le bawọn gbe aṣa iṣẹmbaye wọn larugẹ ko tọ si ipo Ọba.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Fẹmi Joseph fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si jẹ ko ye wa pe kabiyesi ati Olori wa nibi ti aabo wọn ti daju. Bẹẹ lo si tun sọ pe alaafia ti de siluu naa pada.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI