IṢẸJU KAN PERE LO KU KI N DARAPỌ MỌ ẸGBẸ AGBABỌỌLU ARSENAL - RONALDO SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 18, 2019

IṢẸJU KAN PERE LO KU KI N DARAPỌ MỌ ẸGBẸ AGBABỌỌLU ARSENAL - RONALDO SỌRỌ

Gbajugbaja agbabọọlu agbaye nni, Cristiano Ronaldo ti gbogbo awọn agbabọọlu n wo gẹgẹ bi awokọṣe ti sọrọ, o ni diẹ lo ku koun darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, nitori pe oun ti fẹẹ wọle tan, koun too yi ẹsẹ pada.

Ronaldo sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ko ṣe e fọwọrọti sẹyin ninu gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu patapata lagbaaye, ati pe paapaa, oun ko le gbagbe ipa ti Arsene Wenger ko nigbesi aye oun.

Ọdun 2003 ni Ronaldo pinu lati fi ẹgbẹ agbabọọlu Sporting Lisbon silẹ, to si n wa ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo darapọ mọ, ẹnu ọna lati wọ Arsenal la gbọ pe Ronaldo wa ko too yipada lọọ darapọ mọ Manchester United, nibi to ti di olokiki lonii.

Ọmọ bibi orilẹ-ede Portugal to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Juventus lọwọlọwọ bayii lo sọrọ naa lori amohunmaworan ti ITV laipẹ yi nigba to n sọrọ lori bo ṣe pada lati darapọ mọ Arsenal nigba naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI