Ile ẹjọ Tribunal to fikale siluu Ṣokoto ti paṣẹ pe ki Ọnọrebu Ṣahabi Umar lọọ rọ kunle digba ti ajọ eleto idibo, INEC yoo ṣatundi ibo lẹkun Binji, ipinlẹ Ṣokoto latari awọn magomago to waye lasiko idibo to gbe e wọle.
Lara awọn agbegbe idibo ti wọn ni magomago ti waye ni Rumfar Marina ati
Kusa Da Garkar Magaji Margai ni wọọdu Maikulki; Shiyyar Sarkin Aski ni wọọdu Binji ati Tumunin Magaji ni wọọdu Soron Gabas.
Ọnọrebu Bature Mohammed Binji tẹgbẹ oṣelu APC la gbọ pe o gbe ẹjọ lọ sile ẹjọ Tribunal wi pe oun ko gba ibo ti ajọ INEC fi kede akẹgbẹ oun, Ọnọrebu Ṣahabi Umar tẹgbẹ oṣelu PDP sọle, nitori pe magomago wa nibẹ.
Ibo ẹgbẹrun mejila din ni marun un (11,995) la gbọ pe Umar fi bori akẹgbẹ ẹ, Bature toun ni ibo ẹgbẹrun mẹwaa ataabọ (10,580).
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Hamman Idi Polycarp sọ pe ibo ẹgbẹrun kan aabọ ti Umar fi la Bature ko to awọn oludibo 2,378 to forukọ silẹ, nitori naa, ki atundi ibo wa.
No comments:
Post a Comment