ÌYÀWÓ TÓ BÁ FI OORUN DUN ỌKỌ RẸ̀ YÓÒ ṢẸ̀WỌ̀N ỌDÚN MÉJÌ GBÁKO - ỌLỌPAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 13, 2019

ÌYÀWÓ TÓ BÁ FI OORUN DUN ỌKỌ RẸ̀ YÓÒ ṢẸ̀WỌ̀N ỌDÚN MÉJÌ GBÁKO - ỌLỌPAA


Ko si ìròyìn méjì tó tún ń lọ káàkiri àgbáyé báyìí, bí kò ṣe ti bí ọ̀ga ọlọpaa kan lórílẹ̀-ede Ghana ṣe sọ pé iyaale ilé tó bá gbìyànjú láti fi oorun dùn ọkọ rẹ yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbáko gbara. 

Ọ̀gá ọlọ́pàá náà, Ọgbẹni George Appiah-Sakyi to jẹ́ olórí Central Regional fún Domestic Violence and Victim Support Unit (DOVVSU) lọ fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé ẹ̀sùn ìfìyà-ara-jẹni (emotional abuse) làwọn yóò fi kan iyaale ilé tó bá fi oorun dùn ọkọ rẹ. 

Bẹẹ lọ tún sọ pé iyaale kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti wo ṣòkòtò sún lẹgbẹ ọkọ rẹ pẹ̀lú erongba láti fi ẹtọ ọkọ rẹ dùn ún nítorí pé wọn tí jọ tọwọ bọwe àdéhùn gẹ́gẹ́ ọkọ àti aya. 

Àti pé bí iyaale ilé bẹẹ bẹbẹ, àwọn yóò fojú àánú wo ó lati san owó ìtanràn tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún mẹ́fà owó ilẹ̀ Ghana (GH¢6,000), bẹ́ẹ̀ lọ tún jẹ́ kó di mimọ pé tó bá ti pẹ tí irú iyaale ilé bẹẹ bá ti ń hùwà náà, ó ṣeé ṣe kó ṣẹwọn, kò sì tún san owó náà. 

O wa rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọkùnrin, pàápàá àwọn baale ilé tí wọn ba n bá irú adojukọ báyìí pàdé nínú ìgbéyàwó tètè fi tó ileeṣẹ ọlọpaa létí láti lè gbé igbesẹ tó yẹ, káwọn sì lè fìyà tó tọ́ jẹ́ irú obìnrin bẹẹ. 

Appiah-Sakyi tún fìdí ẹ múlẹ̀ pé kii ṣe àwọn obìnrin nìkan ni òfin tuntun yí de, bí kò ṣe pé bó ṣe de àwọn obìnrin náà lo de àwọn ọkùnrin, tó sì ti fi ẹsẹ múlẹ̀ láti ọdún 2007.

Oni iyaale ilé tí ọkọ rẹ bá fi oorun dùn náà láǹfààní láti wá a fi ẹjọ́ sún nílé iṣẹ ọlọpaa, àti pé ọkọ kò gbọ́dọ̀ ronú láti sọ pé òun kò níí jẹ oúnjẹ tiyawo òun bá ṣe silẹ fún un. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI