ẸGBẸ́ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́-JÁDE L'ONDO RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ GÓMÌNÀ AKÉRÉDOLÚ NÍTORÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GIRAMA UNITY - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, September 14, 2019

ẸGBẸ́ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́-JÁDE L'ONDO RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ SÍ GÓMÌNÀ AKÉRÉDOLÚ NÍTORÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ GIRAMA UNITY

Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́-jáde tí ilé ẹ̀kọ́ gírámà Unity tó wà lágbègbè Ode-Aye nijọba ìbílẹ̀ Okitipupa tí rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sì Gomina ipinlẹ náà, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu láti tètè fojú àánú wo ile ẹ̀kọ́ náà, latari ipò tí wọn loo wá, èyí tí wọn sọ pé kò bá ojú mú tó.

Nínú ìpàdé kan tí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́-jáde nílé ẹ̀kọ́ náà, ẹ̀ka tí ọdún 1999 ṣe laipẹ yí ni wọn ti gbé atẹjade kan síta, èyí tí akọ̀wé àti akọ̀wé ìpolongo wọn, Ọgbẹni Jide Jaiyesimi àti Afọlabi Obolo bù ọwọ lu pé bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbà ilé ẹ̀kọ́ nipinlẹ Ondo, kò yẹ kó di ẹgẹrẹ-miti.
 
Wọn ní ọpọ àwọn alágbára nìdí òṣèlú àti àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n, Ọmọwe lorilẹ-ede Nàìjíríà, paapaa nipinlẹ Ondo lo jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọn ti jáde, tí wọn sì ń ṣe dáadáa nìdí iṣẹ́ àti okowo wọn.
Ẹgbẹ́ náà nígbà tí wọn tún ń yan àwọn olóyè tuntun níbi ayẹyẹ ogún ọdún tí wọn tí kẹ́kọ̀ọ́ jáde, ìyẹn Reunion Party ní wọn tí dibo yàn Kọmureedi Fẹmi Ayejusunlẹ gẹ́gẹ́ bíi olùdarí wọ́n.

Nibẹ ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu ọwọ tijọba ipinlẹ naa fi mu ile ẹkọ naa, wi pe o yẹ ki wọn ti wa nnkan si i, nitori pe eto ẹkọ ṣe pataki pupọ, to si yẹ kijọba pese awọn agbegbe amayedẹrun fawọn akẹkọọ.
 Wọn ni ipo ti ile ẹkọ naa wa bayii, ti sọ ogo ati ọla ẹ nu, paapaa bo ṣe jẹ ipo kinni in lo wa tẹlẹ laarin awọn ile ẹkọ to wa ni gbogbo ipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ni bayii, o wa lẹyin patapata.
 
Bẹẹ ni wọn sọ pe ko yẹ ko jẹ pe ile ẹkọ naa to jẹ ibi tawọn olukọọ ti n gba idanilẹkọọ, iyẹn Teachers Training College tẹlẹ ni yoo wa niru ipo ibanilọkan jẹ bayii, nitori naa kijọba dide lati gbe e dide pada, ko si le figagbaga pẹluu awọn ile ẹkọ kaakiri agbaye.

Yatọ si pe wọn rawọ ẹbẹ sijọba, wọn tun ke si gbogbo awọn ẹlẹyinju aanu niluu Ode-Aye, paapaa nipinlẹ Ondo lati dide iranlọwọ fun ile ẹkọ naa.
Nigba to n naa kanminu lori ipo tile ẹkọ naa wa bayii, olori awọn akẹkọọ ni saa ọdun 1999 naa, Ọgbẹni Kuyẹ Pẹlumi sọ pe o ṣeni laanu pe ile ẹkọ to gbe ọpọ awọn eeyan dide nijọba yoo pati, to si jẹ pe awọn ile ẹkọ bii St. Peters niluu Akure; St. Helens niluu Ondo atawọn min in ti wọn ti n wo o gẹgẹ bi aṣiwaju tẹlẹ ni wọn ti wa niwaju ẹ bayii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI