NITORI AṢEMAṢE, IGBAKEJI ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR NILẸ YORUBA, BỌDE SIMEON WỌ GAU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, September 15, 2019

NITORI AṢEMAṢE, IGBAKEJI ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR NILẸ YORUBA, BỌDE SIMEON WỌ GAU

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu ila-ilo ni igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu Labour lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn ẹkun ilẹ Yoruba, Kọmureedi Bọde Simeon wa bayii, latari awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn lo n hu, eyi to fi n ba ẹgbẹ naa loju jẹ.

Ko si nnkan ti wọn loo ko iporuru ọkan ba ọkunrin naa, iyẹn Bọde Simeon bi ko bi wọn ṣe lo n kọ ọrọ si ọga ẹ to jẹ alaga patapata fun ẹgbẹ naa lorilẹ-ede Naijiria lẹnu, to si n fi awọn iwa ẹ tu ẹgbẹ naa ka, paapaa nipinlẹ Ogun.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yi la mu iroyin kan wa fun un yin pe ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun lawọn da alaga wọn, Kọmureedi Abayọmi Arabambi duro gẹgẹ bi alaga, ti wọn si ni ko ṣẹyin aṣẹ ati ontẹ ti wọn ni alaga wọn, Kọmureedi Abdulakadir Abdulsalam wa nibẹ pẹluu.

NJẸ Ẹ TI KA A: NNKAN TO DA WAHALA SILẸ RE E 

Ṣugbọn ti alaga naa, Abdusalam sọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ipade ti wọn ṣe lati fi da Arabambi duro, ati pe ipade naa ko lẹsẹ nilẹ rara, ayederu lasan ni, nitori pe oun ti paṣe pe wọn ko gbọdọ ṣepade kankan.

Ninu lẹta kan to tẹ AWIKONKO lọwọ lọsan oni ni wọn ti pe Kọmureedi Bọde Simeon lẹjọ pe ko wa a dahun iwa ọdalẹ to n hu ninu ẹgbẹ naa, paapaa nipinlẹ Ogun, ati bo ṣe n fi orukọ alaga wọn, Abdulsalam parọ fawọn eeyan kaakiri.

Ohun ti a ri ka ninu lẹta naa, ti alaga patapata bu ọwọ lu sọ pe ki Bọde Simeon wa a ṣalaye laarin ojo meje nipa nnkan to ri l'ọbẹ to fi waaru ọwọ, iyẹn ni ti ipade ẹtanjẹ ati agabagebe to ṣagbatẹru ẹ niluu Abẹokuta lọjọ Tọside, bi bẹẹ kọ, yoo kan idin ninu iyọ, tori pe awọn iwa rẹ tako ofin ẹgbẹ naa ti abala kọkandinlogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI