ỌBASANJỌ FI ONTẸ LU BAALẸ MẸFA NILUU ITELE LỌJỌ KAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, September 18, 2019

ỌBASANJỌ FI ONTẸ LU BAALẸ MẸFA NILUU ITELE LỌJỌ KAN ṢOṢO

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun Tuside ana ni Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ gba alejo gbogbo awọn agbaagba nilu Itele to wa nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta ipinlẹ Ogun, nibẹ lawọn araalu naa ti foju awọn baale wọn tuntun mẹfa han.

Yatọ si agbegbe Ilegbede ti ko mu baalẹ ti wọn yọju latari awọn aawọ to ṣi n jẹyọ lori ẹni ti yoo jẹ Baalẹ wọn, gbogbo awọn agbegbe yooku bii Ilekẹmọ, Ipọtọbọ, Ijana, Iṣumba, Iliwọ ati Olugbode to wa niluu Itele naa la gbọ pe wọn pọn awọn Baalẹ naa lọ sile Baba Ọbasanjọ.

Nibi ipade naa to waye ninu gbọngan ipade ti Oke-Ọna nile Itura Green Legacy Resort niluu Abẹokuta lawọn agbaagba naa ti jẹ ko ye Oloye Ọbasanjọ pe ko tun si aawọ tabi wahala kankan mọ laarin awọn ọmọ ati olugbe ilu Itele, nitori pe awọn ti fọwọsowọpọ, tawọn si ti wa iṣọkan bayii, nitori pe alaafia lo ṣe pataki.

Awọn Baalẹ tuntun naa ni: Oloye Adelaja F. Faṣina ti agbegbe Iliwọ; Oloye Mọnsuru Ọlayinka Balogun ti agbegbe Ilekẹmọ; Oloye Ọwọtolu Kazeem ti agbegbe Ijana; Oloye Fatai Akapo ti agbegbe Iṣunba; Oloye Rasheed Ajasa ti agbegbe Ipọtọbọ; ati Oloye Lateef Rufai ti agbegbe Olugbode.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, a gbọ pe ko din ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu (500,000,000milion) naira lowo ti wọn ti na latigba ti wahala naa ti bẹrẹ ni nnkan bí ogoji ọdun sẹ́yìn, lati wa iyanju si i, ṣugbọn lẹyin ti okodoro foju han, lawọn eeyan naa to o ṣẹṣẹ gba lati gba alaafia laaye lati jọba laarin wọn, ki ilọsiwaju le tubọ de ba wọn.

Nigba to n fi idunu ẹ han, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọ pe "Oni ni inu mi dun ju pẹlu bi ẹ ṣe sọ pe ẹ ti gba alaafia ati iṣọkan laaye. Ifẹ ṣe pataki ninu idagbasoke ilu, o si ṣe koko lawujọ wa.

"Bo ṣe yẹ ko ri niyẹn. Omi lawa eeyan, ti a si n ṣan kaakiri, ati pe to ba ṣan sibi kan lonii, ibomin in lo tun maa ṣan si to ba digba min in. Ẹ jẹ ka gbagbe itan tabi arọba, awọn nnkan to n ṣakoba fun alaafia gan an ni itan ati arọba."

O wa a dupẹ lọwọ awọn ilu naa ti Oloye Abraham Idowu Akanle lewaju wọn fun igbesẹ ti wọn gbe naa, toun si mọ pe agbegbe kan toku naa yoo yan baalẹ wọn laipẹ.

Nigba to n gba ẹnu gbogbo awọn agbaagba naa sọrọ, Oloye Yahya Oyewọle ti wọn tun n pe ni Baba Ọdan sọ pe "Inu mi dun pe nnkan bayii n ṣẹlẹ loju aye mi. Ọkan wa si balẹ bayii pe a le sun ka diju mejeeji. A wa n fi asiko yi gboriyin fun Baba wa, Oloye Ọbasanjọ fun akitiyan ẹ lati pana wahala naa."

Síwájú sii ni Oloye Akanle gbawọn Baálẹ̀ náà lamọnran pé kí wọn fọwọsowọpọ láti mú idagbasoke bá ìlú Itele, kí wọn sì dìde ogún sì ẹnikẹni tó bá kọjá ààyè ẹ láti dá sí nnkan ti ko kan án. 

Bẹẹ lo kilọ fáwọn ajagungbalẹ to ni ìpinnu láti dìde siluu Itele wí pé kí wọn má gbìyànjú ẹ wo, nítorí pé wọn yóò gé ìkà abamọ sẹnu bí ọwọ bá tẹ wọn, àti pé omi tuntun tí ru bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI