NITORI FOONU, BAALE ILE MEJI JABỌ SINU KỌNGA L'EKITI, LOJU ẸSẸ NI WỌN KU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, September 8, 2019

NITORI FOONU, BAALE ILE MEJI JABỌ SINU KỌNGA L'EKITI, LOJU ẸSẸ NI WỌN KU

Ṣe lọrọ di boolọ o yago laarọ ọjọ Aiku Sande oni nigba ti wọn lawọn baale ile meji kan ti wọn yan iṣẹ agbaṣẹ ṣe laayo nipinlẹ Ekiti ko sinu kọnga lasiko ti wọn n gbiyanju lati yọ foonu to jabọ sinu kọnga naa.

Abule kan ti wọn pe Anaye to wa nijọba ibilẹ Emurẹ la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye. Foluṣọ Ajayi ti wọn tun n pe ni Vosco ati ọkunrin kan tọpọ awọn eeyan n pe ni Alaaji, ẹni ti wọn lọmọ Ebira nipinlẹ Kogi ni lawọn meji naa ti a gbọ pe foonu lo ran wọn lọ sọrun alakeji.

Ohun ti a gbọ ni pe ọkan lara awọn meji lo n gbiyanju lati pọn omi to fẹẹ lo lati dana, asiko naa la gbọ pe ẹni kan pe e lori foonu ẹ, bo si ṣe n gbiyanju lati yọ ọ ni foonu naa jabọ sinu kọnga ti wọn loo jinna gan an.

Bi foonu naa ṣe jabọ la gbọ pe o gbiyanju lati yọ ọ, ṣugbọn ṣe ni wọn sọ pe ẹsẹ yọ gẹẹrẹgẹ to si fẹẹ jabọ sinu kọnga naa, eyi lo mu ki ekeji ẹ naa sare debẹ lati doola ẹ, to si jẹ iyalẹnu pe ṣe lawọn mejeeji jọ jabọ lẹẹkan-naa.

Awọn Hausa marun ọtọọọtọ la gbọ pe wọn lọọ wa lati yọ oku awọn eeyan naa, to si jẹ pe okun ni wọn so mọ lọrun ki wọn too fi gbe wọn jade.

Bẹẹ la gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI